Wednesday, April 30, 2014

Ori To Kẹ Yoruba bọ, wọn ni ‘Oun gbogbo lọwọ ori ni’.


Edumare tun wa fi awọn nka mere-mere se ‘ẹsọ ori’
Bi oju, ahọn, eti, eyin ati ọpọlọ
Oju ni fitila ara, ahọn ni ọrọ, ọrọ nii yọ obi lápò, oun lo tun yọ ọfa lápó
Bi eti o ba gbọ yigin, inu kan o kin bajẹ,
Bẹẹ sini, bi eyin ba ti ka, ile ẹrin ti woo
Ti Yoruba ba sọ wipe ọpọlọ eyan ti jọba, ẹ ma fura si iru ẹni bẹ o.
Yoruba a gbe oriyin fun Ori…’Oritookẹ! Ori ẹni lapesin,

Monday, April 28, 2014

EJA N'BAKAN: Itan Eja Ni Abi Akan

AKAN ati EJA je pataki ninu awon opolopo omo Yeyemoja Olokun. Ni ojo kan ni Yeyemoja pe omo re EJA-(fish) pe ki o lo ba ohun sin gbese. Nigbati Eja-(fish) de odo onigbese, ni o ba (tu ito soke, lo fi oju gbaa). Ni o baraje, O soro abuku ohun ete si oni-gbese.
Iwa ibaje yii, mu ki inu bi onigbese, o pinu pe ohun ko ni gbesee kan san. Eja(fish) kori sile, ko ri gbese naa gba, o rele pelu ofo; ojo-keji oja.

Saturday, April 26, 2014

Ekú déédé ìwòyí o! - Ìbéèrè mi nì

Ekú déédé ìwòyí o!
Èyin èèyàn mi lórí ètò yí, ejòwó ebámi dásí òrò yí, bí àwon baba wa nílè yorùbá báfé júbà won a máa so báyìí pé;
ÌBÀ AKÓDÁ, ÌBÀ ASÈDÁ, ÌBÀ ÀTIWÁSÁYÉ. Ìbéèrè mi nìní; tani akódá?
Tani Asèdá?
Kíni àtiwásáyé?

Thursday, April 24, 2014

ERIN WO. Erin wo, Ajanaku sun bi oke.


 Eyin ka ile erin ti wo , Afemojo ku enu isa n s'ofo............................. Lana ojo ketalelogun , osu Kerin ni iku wole to mu Alhaji Moshood Ayinde (Olorun Esan ) lo. Ojulowo onisowo ,omo Apomu, lo nile yi ao ri o mon , Parakoyi oloselu o digba o, ilu London niku ti pa baba ni eni odun metalelaadorin (73 years). Baba Biola o digba .Iba se pe a ki ku laye , Olorun Esan a ba so pe iku jare re....



Femi Ojewale

ASIRI TU: ni adugbo Aperin ni ilu lbadan


 Laipe yi ni owo te obinrin kan ni adugbo Aperin ni ilu lbadan , nigba ti owo awon Olopa ti o n dagbo mo awon ti won n fi omo s'owo eru te Hellen ati oko re ogbeni Temitope lori esun pe won n fi awon omo k'ogbo k'ogbo ti won ko ti I to omo odun mejidinlogun se ise Asewo . Mo gbe osuba bamba fun Komisana ati awon Olopa ilu Ibadan fun aseyori ise naa. E ku ise o


Femi Ojewale

NNKAN N BE. Ireti obi ni pe ki obi jere omo l'ojo ale


Ireti obi ni pe ki obi jere omo l'ojo ale.Sugbon ni ti Elizabeth ko ma ri bee o, Looto,o lo s'ile iwe alakobere,o lo si girama leyin naa lo wole s'ile iwe Obafemi Awolowo Yunifasiti,lle lfe nibi ti o ti n ko ise imo isegun Oyinbo.o ku bi osu meta pere ki o pari eko re ni awon osika eda kan lo fi tipa tikuuku ba a sun ti won si tun pa a, gege bi a se gbo,won ni omo jeje ni Elizabeth ki o to di pe won da emi re legbodo ti won si yo awon nkan kan lo lara re



Femi Ojewale

Sunday, April 20, 2014

EBI OOOO !! awon Boko Haram

!!! Ninu ose ti a wa yi ni awon Boko Haram se saka ni ibudoko kan ti o gbajumo ni ilu Abuja ti ogunlogo emi si sonu sinu ikolu naa bakan naa ni omilegbe ero farapa ti won si ko won lo si ile iwosan Asokoro nilu Abuja. Sugbon ni bayi o , awon eniyan naa ma ti n kigbe ebi o , ninu oro re Minisita fun eto ilera so pe ojuse jije mimu won wa lowo awon alase ile iwosan naa . Se o ye ki o ri bee ? Oro re e o , eyin omo Nigeria , se ki ebi tun lu won pa ni ?

IDARIJIN NLA NIYI O !!! afi bi igba ti eniyan n wo Sinima ofe ni

 Huumm,afi bi igba ti eniyan n wo Sinima ofe ni gbogbo eniyan se de enu sile ni ojo'bo (Thursday) ti o koja yi ni Orile ede Iran nibi ti won ti fe ye igi fun Bilian ti o pa omo kan soso ti iya arugbo kan bi,o ku iseju aaya mewa pere ki won ye igi fun okunrin apaayan naa,ni iya agba yi yo lokankan,bi awon oluworan se ri iya yi ni opolopo won bu sekun sugbon dipo ki iya yi bu sekun n se lo sunmo eni ti o pa omo re ti o si so pe oun darijin in. O ga oooo


Thursday, April 17, 2014

ODU EJI OGBE – The chant Ori koo da mi ‘re – Ori bless me abundantly


Orisa ma jee nsowo asenu – Orisa do not let me labor in vain
Adifa fun okankan lenirunwo Irunmole – Divinated for 401 + 1 Orisa
Nigbati won ntode orun bo wa si ode aiye
When they were to descend from heaven into the world
Ori lo koko da Orunmila si Oke-Igeti -Ori first created Orunmila in Igeti-Hills
Ori koo da mi ‘re – Ori bless me abundantly
Orisa ma jee n sowo asenu -Orisa do not le me labor in vain

Wednesday, April 16, 2014

Video: How The African People See European Culture - a must see!

ORO BURUKU ATI ERIN: Imaobong Udoh ni arabinrin yi n je


Imaobong Udoh ni arabinrin yi n je , o ti wa ni ago awon olopa ni ipinle Akwan lbom lori esun pe o ta omo bibi inu ara re ni#260,000 omo ojo meta fun Regina ati Mfon James ti won je tokotaya , Bakan naa ni owo awonolopa ti te arabinrin Comfort Herry eni ti o gbebi fun lmaobong ati ogbeniEmmanuel Okon ti o je alarina bi omo ojo meta naa se di rira.  Saaju ni baba omo yi ogbeni Udoh ti fi ejo sun ni ago olopa pe omo oun ti sonu ki owo to wa te awon asebi naa. Ninu oro tire , oko obinrin ti won fi esun ogbeni James ni oun ko gbe ile , iyawo oun kan pe oun pe oun loyun ni ati pe ise oun ko fun oun laaye ati pe awon onisegun ti so fun oun lati maa daamu re.
Oro ree oooooooo

ORO RE E OOOOO!!! Eyin odomobinrin wa . Annabella Zwyndlla niyi

Oro re e o , eyin odomobinrin wa . Annabella Zwyndlla niyi , okan pataki ninu awon irawo osere ni ile yi ati ni oke okun , omo bibi lpinle Adamawa ni orile ede Nigeria ni i se . Oun ti o ya ni lenu ni pe laarin ogooro obinrin ni Nigeria , obinrin yi ma ti fowo soya o pe ni ojo aye oun okunrin kankan ko ti gori oun ri , ni bayi o si ti pe eni odun meedogbon (25 years but still remain virgin) pelu bi o se lewa to ti awon okunrin si maa n sare te lee leyin to.
Ninu oro re o ni bi ko tile rorun , sugbon oun ti pinu pe oko ti oun ba fe ni yo ja ibale oun. o ni bi o tile je pe ko si iru fiimu ti oun ko le sibe ko so oun di asewo rara.
Tabi e ko wa ri pe awon omo gidi si tun wa ninu ise tiata bi ti Olootu ORO TO N LO alaya ma l'ale. Huuuuuummmmmmmm.

Tuesday, April 15, 2014

Oro Awon Boko Haram Yi Toju Su Wa O !!!!

 Lana ojo keedogun osu Kerin odun 2014 ni deedee agogo mefa aabo idaji ni bombu bere si ro l'otun l'osi ni okan pataki ninu awon ibudoko ti o wa ni ilu Abuja , ti oro is di bi o ko lo ki o yago l'ona . Ninu ikolu awon Boko Haram yi ni eniyan mokanle laadorin (71 people) ti gbemi min nigba ti eniyan merinlelogofa (124 people) fara pa yana yana. Oro yi toju su wa o , omo Nigeria.

Femi Ojewale

WAHALA WA O: Orile ede ti egberun lona edegbeta odo 500,000


WAHALA WA O !!!!! Kin ni e ro pe yoo ma sele ni Orile ede ti egberun lona edegbeta odo 500,000 ti kowe mo n wase si ile ise asobode ti won ti fe gba egberun merin 4,000 eniyan pere , eyi ti o fa iku opolopo awon odo laipe yi. Hummn, laipe yi ni owo te awon odo yi ni adugbo Leki ni ilu Eko nibi ti won ti n sise yahoo , awon odo ti won ko ti i pari eko yunifasiti won. Nibo la n lo l'orile ede yi nibi ti oro awa odo ko ti kan awon asiwaju wa. O ma se oooooooo !!!!


IBUKUN YANTURU - Opolopo ni ona ti ibikun

 Se opolopo ni ona ti ibikun maa n gba wole wa , bi ko je nipa owo , o le je ibukun alafia tabi opolopo dukia , koda o le je ibukun omo bibi pelu. Laipe yi ni obinrin ti o duro si aarin awon ero yi loyun,erongba oun ati oko re si ni pe yoo fi oyun naa bi ibeji sugbon si iyalenu gbogbo olugbe ilu India ati awon dokita ti o gbebi fun un , omo mokanla ni obinrin naa fi oyun inu re bi losan ana.Tabi e ko ri pe onise ara ni Olorun oba , ki Olorun da won is o

Monday, April 14, 2014

Yoruba religion - South-West Nigeria springs


When we talk about Yoruba or Yoruba religion, the African race particularly the Yoruba people of South-West Nigeria springs to mind. Nope! There are Yoruba aboriginals in Togo and Benin Republic.


There are native Caribbeans and South Americans who have adopted Yoruba culture and most interestingly, they passionately follow our own ancestral faith “The Yoruba Religion” called Santeria (Lucumi) in the Americas.

Photo: Babalawo Fabunmi performing the Ifa divination on some Ifa devotees.

Sunday, April 13, 2014

Oriki Ibeji (Twins)


This Panegyric Is Dedicated To Our 'Twins' Members
Ejire oyila winiwini loju orogun, ejiworo loju iya re
Mba bejire mbayo, O be kisi be kese, ofese me jejeji be sile alakisa
O so alakisa di onigba aso, okan ni mba bi mba yo, sugbon meji lo wole tomiwa,
Gbajumo omo ti ngba ikunle iya, ti ngba idobale lowo baba to bi won lomo

Ejire ara isokun, edunjobi omo edun tin sere ori igi

Taani eni naa to so wipe kosi olorun?

 Ayafi omugo eniyan lo le so wipe olorun kosi, oba ara lolorun mi, iwo gba adura lasale yii wipe oba to fi aaye gba eye loju orun tofi aaye gba eja nisale odo tofun ikan ni oye lati parapo kole alaranbara, tofi aaye gba oju, imu ati enu ni etelese ti eniyan si nrin ti ko ni lara, faaye gbami ninu ebi mi ki nle se rere amin

Abamo Ni Gbeyin Oro Abamo

Laipe yi ni owo awon Olopa ipinle Oyo te awon omokunrin meji yi, awon mejeeji ,Clement Rankin eni odun metadinlogbon (27) ati Joshua Samuel (25) ni won jo je ore ti won ti jingiri ninu jija okada gba ni ilu lbadan , sugbon ninu ose ti o koja ni owo palaba won segi nigba ti won gun okada lati Mokola ni ilu lbadan nigba ti won de Samonda ni won ba fa ada yo si olokada naa ti oun naa is figbe ta ni awon ara adugbo ba gba bo won ti owo si te awon mejeeji. Ninu oro re ni ago olopa Rankin ni gbogbo igba ni baba oun ti maa n kilo fun oun lati fi iwa ipanle sile,sugbon ni bayi oju oun ti ja a bayi oooooooo

~Femi Ojewale

ITAN: Ni ilu ti mo de


Ni ilu ti mo de yi ni won ti je k'oyemi pe pipa ni won maa n pa awon Agunbaniro ti o ba fun awon Omobinrin won loyun. N ko se meni se meji, mo gbe apo irinajo mi, o di'lu Abuja lodo Roselini, arabinrin ti o ba mi se'to bi won se gbemi lo si ilu Kantaga yii, ibi ti awon Obinrin rin won ki i ti ba awon Agunbaniro lo.
Ero meji ni o wa si mi lokan: Akoko ni pe n ko so pe n o k'enu Ife si awon Omobinrin ibe o, sugbon ise temi gege bi Oluko nibe, n je ko ni si igba ti emi ati awon omo wonyi yoo ma sere bi kaf'orow'oro ni? Abi ki Oluware kan dake kale bi Olundu ni won fe? Ekeji ni pe awon Omobinrin ti o wa nilu yii rewa ju ki n ma bawon sere oge lo. Won pon dele bi olele awe. Oju won gun rege. Ikebe won ju Olumo rooki lo. Irun ori won n bena yan-yan-yan bi igba ti ara ba san loju orun.

Saturday, April 12, 2014

BOKO HARAM KIN LO DE.

 Egbinri ote bi a se n pa okan , ni okan n ru . Ojo monigbabe ni ojo oni je ni ilu ati lpinle Borno nibi ti awon Boko Haram ti dana ibon, ofa ati bomb mo awon omo ti ko mowo ti won ko mo ese lara. Jeje ku ni awon omo wonyii , ti opo ninu won je alejo n lo se idanwo JAMB sugbon ti ogunlogo won ko mo pe titan yo de ba awon lojo oni , bi won se n ju bomb lotun ni won n yinbo losi ti opo awon omo yi si n sa bo si owo awon eni ibi wonyii.

Friday, April 11, 2014

Aroko - Yoruba Parabolic Message

Aroko was a way by which pre-literate Yorubas used to send message over long distance in the olden days. It is done by sending some symbolic items to the person for whom the message was meant through a third party; and the message would be understood by the receiver.
For an instance in December 1854, the Awujale of Ijebu sent such a parabolic message to Rev. David Hinderer who was then resident in Ibadan. The Aroko he sent to him was this: ten cowries strung together and a seed of the orange fruit. The meaning of the Aroko is this: come, it is well. Can you spot the correlation between the items sent and its meaning?

Tuesday, April 8, 2014

The Unforgotten Yoruba

Funmilayo Ransome Kuti born 25 October 1900 in Abeokuta, she was a prominent Yoruba woman and an anti-colonial activist, a teacher and a politician. She was described by many as the doyen of women's rights in Nigeria and the Mother of Nigeria. She founded and was the leader of Abeokuta Women's Union on a campaign against arbitrary taxation of women, a pressure group that had over 20,000 membership, the struggle which led to the abdication of the Egba King Oba Ademola II in 1949.

Sunday, April 6, 2014

The Concept Of Marriage In Yorubaland

Marriage is one of the oldest institutions among Yoruba, it marks the end and the beginning of a new era between two different individuals, who agreed to live together, and through their union creates everlasting friendship between homes of their birth.

In times past, marriage matters were never left in the hands of prospective couples, rather, families’ affairs. Several steps were required before marriage could be consummated, although, things have really changed; yet, some of these steps are still valid and observed in a marriage journey by couples, because of their cultural relevance.

Saturday, April 5, 2014

Adeshina Remigio Herrera (Obara Meji) Adeshina (Crown of Fire): founding fathers of Ifa

Adeshina Remigio Herrera (Obara Meji)Adeshina (Crown of Fire) is credited as being one of the most important founding fathers of Ifa in Cuba. A Yoruba born in Yorubaland and initiated as a babalawo there, was enslaved and taken to Cuba as a young man in the 1830s.

Wednesday, April 2, 2014

We are learning on Ọmọ Oódua Today…... What is the Yorubs Word for ......


We are learning on Ọmọ Oódua
Today…...
WHAT'S THE YORUBA WORD FOR STAR?? (Pictured)
With this approach, we have learned that:
African Star Apple is Agbalumo
Ground Hornbill is Akalamagbo
Eagle is Idi
Pouched Rat is Okete

Tuesday, April 1, 2014

APALARA, EJIKA N’IYEKAN...



...Oju ni atọkun ara, Iwa ni atọkun ẹwa
ọpọlọpọ obinrin lo ti sọ’wa nu, Igba-aya wọn lo nse atọkun ẹwa fun wọn
Bi ẹlomi gba’rodan awọn tibi mejeeji tan, ti wọn ko bo se yẹ ki wọn ko
gbogbo ẹ o wa ran’ju kankankan, wọn wan ta tokunbọ ”no testing” ka kiri igboro
O ti gbagbe wipe, ẹni to ba ta ọja yeepẹ, dandan ni ko gbowo okuta.

ST