Tuesday, April 1, 2014

APALARA, EJIKA N’IYEKAN...



...Oju ni atọkun ara, Iwa ni atọkun ẹwa
ọpọlọpọ obinrin lo ti sọ’wa nu, Igba-aya wọn lo nse atọkun ẹwa fun wọn
Bi ẹlomi gba’rodan awọn tibi mejeeji tan, ti wọn ko bo se yẹ ki wọn ko
gbogbo ẹ o wa ran’ju kankankan, wọn wan ta tokunbọ ”no testing” ka kiri igboro
O ti gbagbe wipe, ẹni to ba ta ọja yeepẹ, dandan ni ko gbowo okuta.

Iwalẹwa ọmọ eniyan..kilode to fi jẹ wipe..
Iwa ti doun igbagbe, ẹwa lasan ti wa doun amuyangan l’awujọ?
ọmọ t’aye ba bi l’aye n pọn, orukọ to wu ọmọ l’ọmọ njẹ lẹyin odi
ẹlomi a ni oun "Ibadiaran" a tun ti ri "engineer Ojuloge"
gbogbo ”Sulia kan, Ayetoro kan”, sebi gbogbo wa la mọ ’gbẹyin ọrọ.

Wọn ni amukun ẹru ẹ wọ, o ni oke lẹ n wo, ẹ wo ’salẹ
Igba to jẹ wipe ọja awọn Orekeniwa o ta mọ, Orekelẹwa ni gbogbo okunrin n wa kiri.
Iwalẹwa ọmọ eniyan, Arugbo soge ri o.
Iwọ awẹlẹwa bi ododo...Lootọ igba ara laabura,
sugbọn ẹ ma fi iwa kun ẹwa..ẹwa dabi alejo, o sese ko ma bani d’ọjọ alẹ.
bi ẹwa ba se bẹ to rẹ danu bi ododo, iwa nikan ni kuni ku lawujọ.

By: Raymond Ajeigbe

No comments:

Post a Comment

ST