Sunday, April 13, 2014

ITAN: Ni ilu ti mo de


Ni ilu ti mo de yi ni won ti je k'oyemi pe pipa ni won maa n pa awon Agunbaniro ti o ba fun awon Omobinrin won loyun. N ko se meni se meji, mo gbe apo irinajo mi, o di'lu Abuja lodo Roselini, arabinrin ti o ba mi se'to bi won se gbemi lo si ilu Kantaga yii, ibi ti awon Obinrin rin won ki i ti ba awon Agunbaniro lo.
Ero meji ni o wa si mi lokan: Akoko ni pe n ko so pe n o k'enu Ife si awon Omobinrin ibe o, sugbon ise temi gege bi Oluko nibe, n je ko ni si igba ti emi ati awon omo wonyi yoo ma sere bi kaf'orow'oro ni? Abi ki Oluware kan dake kale bi Olundu ni won fe? Ekeji ni pe awon Omobinrin ti o wa nilu yii rewa ju ki n ma bawon sere oge lo. Won pon dele bi olele awe. Oju won gun rege. Ikebe won ju Olumo rooki lo. Irun ori won n bena yan-yan-yan bi igba ti ara ba san loju orun.

II
Mo de Abuja ni ojo aje. N ko si ba Roselini ni'le. Ibi ti mo ti n gbiyanju lati pe ero Ibanisoro re ni mo gbo lori agbohunsafefe pe Ijoba so pe oun yoo ran awon eeyan lati lo s'ayewo awon Agunbaniro ti won gbe lo si ilu ati Igberiko kookan ni Ojo Isegun.
Oogun ako bo mi wa. Nigba ti n o wo oju aago, aago mejo ale ti lu. Idiko ya...
E ma bami kalo

No comments:

Post a Comment

ST