Monday, April 28, 2014

EJA N'BAKAN: Itan Eja Ni Abi Akan

AKAN ati EJA je pataki ninu awon opolopo omo Yeyemoja Olokun. Ni ojo kan ni Yeyemoja pe omo re EJA-(fish) pe ki o lo ba ohun sin gbese. Nigbati Eja-(fish) de odo onigbese, ni o ba (tu ito soke, lo fi oju gbaa). Ni o baraje, O soro abuku ohun ete si oni-gbese.
Iwa ibaje yii, mu ki inu bi onigbese, o pinu pe ohun ko ni gbesee kan san. Eja(fish) kori sile, ko ri gbese naa gba, o rele pelu ofo; ojo-keji oja.



Yeyemoja ba tun ke si Alakan-(crab) pe ki o ba ohun lo sin gbese.
Nigbati alakan(crab) de odo oni-gbese, ti irele iwa pelu ite-ri-ba ti a mo si. Iwa omo-lu-wa-bi ni Alakan fi jise fun oni-gbese. Yoruba bo wonni; Oro tutu ni n mu obi jade lapo, Oro-buruku ida ni n yo. Ni oni-gbese ba wole, o si san gbese fun Alakan, ni Alakan ba koredele.
Oni-gbese ba gbera o di ile Yeyemoja-Olokun seniade, Nigbati o de odede Yeyemoja, o wipe, nigba-ku-gba ti o ba fe ran onise si ohun: Dakun ma se ran omo Eja si mi mo, Wipe omo Alakan ni ohun fe.
E yii lo mu awon agba Yoruba wipe;
"Ase ye ni ti Alakan-Amu-bo ni ti omo Eja"
Idi niyii ti awon Yoruba se ma n se asamo pe;
EJA N' B'AKAN
By: Fasegun Falade

1 comment:

  1. O wa yemi wayio one would have thought eja is the Yes and akan is the No cos iEja is oved by almost everyone

    ReplyDelete

ST