Sunday, April 13, 2014

Oriki Ibeji (Twins)


This Panegyric Is Dedicated To Our 'Twins' Members
Ejire oyila winiwini loju orogun, ejiworo loju iya re
Mba bejire mbayo, O be kisi be kese, ofese me jejeji be sile alakisa
O so alakisa di onigba aso, okan ni mba bi mba yo, sugbon meji lo wole tomiwa,
Gbajumo omo ti ngba ikunle iya, ti ngba idobale lowo baba to bi won lomo

Ejire ara isokun, edunjobi omo edun tin sere ori igi

Epo nbe, ewa nbe, aya mi oja lati bi ibeji
Eni ejire nwu bi, Ki o yaa niwa tutu, nitori osonu ile kii bi ejire
Oninu ire ni bi edunjobi oba omo
Taiyelolu ma yo se se, Akehinde gbegbon mayo se se
Ejire oyila, ema yo se se, nbabi edunjobi nba yo pe mobi oba omo.
Edumare bawa da awon Ibeji wa si

No comments:

Post a Comment

ST