Showing posts with label Ni ilu ti mo de. Show all posts
Showing posts with label Ni ilu ti mo de. Show all posts

Sunday, April 13, 2014

ITAN: Ni ilu ti mo de


Ni ilu ti mo de yi ni won ti je k'oyemi pe pipa ni won maa n pa awon Agunbaniro ti o ba fun awon Omobinrin won loyun. N ko se meni se meji, mo gbe apo irinajo mi, o di'lu Abuja lodo Roselini, arabinrin ti o ba mi se'to bi won se gbemi lo si ilu Kantaga yii, ibi ti awon Obinrin rin won ki i ti ba awon Agunbaniro lo.
Ero meji ni o wa si mi lokan: Akoko ni pe n ko so pe n o k'enu Ife si awon Omobinrin ibe o, sugbon ise temi gege bi Oluko nibe, n je ko ni si igba ti emi ati awon omo wonyi yoo ma sere bi kaf'orow'oro ni? Abi ki Oluware kan dake kale bi Olundu ni won fe? Ekeji ni pe awon Omobinrin ti o wa nilu yii rewa ju ki n ma bawon sere oge lo. Won pon dele bi olele awe. Oju won gun rege. Ikebe won ju Olumo rooki lo. Irun ori won n bena yan-yan-yan bi igba ti ara ba san loju orun.

ST