Showing posts with label BOKO HARAM. Show all posts
Showing posts with label BOKO HARAM. Show all posts

Saturday, September 13, 2014

Ijamba Se IKo Boko Haram


Ni asale ojo isegun ti o koja ni awon odo iko oju lalakan fi s'ori ni ijoba ibile Michika ati Madagali ni ipinle Adamawa so fun awon iko Boko Haram pe ma f'oko mi s'ona ojo kan ni eniyan maa n ko o , awon odo yi ti lo go sinu igbo nigba ti won ri pe awon Boko Haram ti wo ilu awon , loju ese ni awon odo ijoba ibile mejeeji gbeyin yo si awon Boko Haram ti won si pa Ogorin (80) ninu awon iko Boko Haram ni ifona f'an su. Nigba ti awon iko Boko Haram ri pe eko ko se oju mimu mon ni won ba fi eyin be lu igbe ti won si juba ehoro. A dupe lowo awon odo wonyi fun akinkanju won ati ai s'ojo won. E ku ise oooooo


Femi

Sunday, June 15, 2014

OWO TI TE WON O !!! Owo te Meta ninu awon omo iko gbemi gbemi Boko Haram ni ojo eti


 
Meta ninu awon omo iko gbemi gbemi Boko Haram ti won pa opolopo eniyan laipe yi ni Ijoba Ibile Gwoza ni iko JTF ti te ni ijeta ojo eti , enikan ti awon iko naa du egbon re bi eni du eran lo da okan mo ninu keke Maruwa ti won jo wo , oju ese ni o figbe ta pe oun mo okunrin ti o joko ti oun gege bi okan ninu awon omo iko Boko Haram nigba ti owo iya ba a daadaa lohun naa ba naka si awon meji miran pe ara kan ni awon , loju ese ni won si fa won le olopa lowo .

Femi

Sunday, May 18, 2014

Omi Tan Leyin Eja Won: owo awon omo ogun JTF te Mejo ninu awon gbemi gbemi Boko Haram

OMI TAN LEYIN EJA WON. Mejo ninu awon iko gbemi gbemi Boko Haram miran ni owo awon omo ogun JTF Nigeria ma tun ti te bayi ni abule Goym ni ijoba ibile Dikwa ni ipinle Borno nibi ti won ti jade wa pelu oko akero Hilux pelu keke alupupu meji lati wa ra onje ati aso . Gege bi arigbamu iroyin ti a gbo lati Olu famous ni pe awon mejo yi ti jewo pe awon omo ile iwe ti won ji ko lojosi wa ninu igbo Sambisa , awon ti owo te naa ti jewo ibi ti awon die wa , eyi lo tun mu ki owo te opolopo won.

Femi Ojewale‎

Owo Palaba S'egi: Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram



Ko din ni Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram ti won bo sowo ibon awon apapo omo ogun JTF ti orile ede yi. Ninu ija naa ti o gbona jan jan ninu igbo ti won n pe ni igbo Lamba , ni ijoba ibile Gwaram ni ipinle Jigawa ni ibon awon soja naa ti gbemi Ogota awon Boko Haram ti gbogbo ileto ti o wa ni agbegbe naa si kan gbinrin gbinrin nigba ti won n gburo ibon lotun losi . Ki Olorun tubo maa d'abo re bo wa oooooo


Femi Ojewale

Tuesday, April 15, 2014

Oro Awon Boko Haram Yi Toju Su Wa O !!!!

 Lana ojo keedogun osu Kerin odun 2014 ni deedee agogo mefa aabo idaji ni bombu bere si ro l'otun l'osi ni okan pataki ninu awon ibudoko ti o wa ni ilu Abuja , ti oro is di bi o ko lo ki o yago l'ona . Ninu ikolu awon Boko Haram yi ni eniyan mokanle laadorin (71 people) ti gbemi min nigba ti eniyan merinlelogofa (124 people) fara pa yana yana. Oro yi toju su wa o , omo Nigeria.

Femi Ojewale

Saturday, April 12, 2014

BOKO HARAM KIN LO DE.

 Egbinri ote bi a se n pa okan , ni okan n ru . Ojo monigbabe ni ojo oni je ni ilu ati lpinle Borno nibi ti awon Boko Haram ti dana ibon, ofa ati bomb mo awon omo ti ko mowo ti won ko mo ese lara. Jeje ku ni awon omo wonyii , ti opo ninu won je alejo n lo se idanwo JAMB sugbon ti ogunlogo won ko mo pe titan yo de ba awon lojo oni , bi won se n ju bomb lotun ni won n yinbo losi ti opo awon omo yi si n sa bo si owo awon eni ibi wonyii.

ST