Friday, September 26, 2014

Ko Se Duro Wo !


Ko se duro wo, bo se nlọ la ntẹle…ohun awọn ọmọ igboro ni
Ko kuku si irọ nbẹ, Yoruba gan sọ wipe ‘atatọ ni’, bo ba se nta, ni ko ma tẹle
ọdẹ k’ọdẹ to ba ta, ti o tẹle, iru ẹran bẹẹ loun d’ẹran idin
Iwọ kawe gboye rẹpẹtẹ, ori ‘what will be will be’ lo duro le,

Tuesday, September 23, 2014

Nje O Boju Mu Kii Abiyamon Ma Fun Omo ... ??



 Kii Abiyamon Ma Fun Omo Re Ni oyan N'Ibi Ti Opolopo Eniyan Wa. Beni Tabi Beko???

Tuesday, September 16, 2014

LO BA TAN: Kin lo le mu ki eniyan ri iku n'ile ki o si maa f'owo to o ni imu?


Kin lo le mu ki eniyan ri iku n'ile ki o si maa f'owo to o ni imu , bee gege ni oro okunrin ti e n wo yi ri ni adugbo Iju ni ilu Eko. Okunrin ti enikeni ko mo eye ti o su u yi ni won sa dee dee ba ti o ti gan mon ero amunawa , ibeere awon eniyan ni pe kin ni o wa de ibe sugbon igbagbo awon kan ni pe o seesee ki o je pe okunrin naa fe tu awon eroja ina kan lati lo taa a ni o fi ba iku re pade. Imoran ORO TO N LO ni pe ki a maa s'ora ooooo.
Femi

Saturday, September 13, 2014

Ijamba Se IKo Boko Haram


Ni asale ojo isegun ti o koja ni awon odo iko oju lalakan fi s'ori ni ijoba ibile Michika ati Madagali ni ipinle Adamawa so fun awon iko Boko Haram pe ma f'oko mi s'ona ojo kan ni eniyan maa n ko o , awon odo yi ti lo go sinu igbo nigba ti won ri pe awon Boko Haram ti wo ilu awon , loju ese ni awon odo ijoba ibile mejeeji gbeyin yo si awon Boko Haram ti won si pa Ogorin (80) ninu awon iko Boko Haram ni ifona f'an su. Nigba ti awon iko Boko Haram ri pe eko ko se oju mimu mon ni won ba fi eyin be lu igbe ti won si juba ehoro. A dupe lowo awon odo wonyi fun akinkanju won ati ai s'ojo won. E ku ise oooooo


Femi

Thursday, September 11, 2014

ARANBARA! Mewa n sele l'oke eepe ,



Okunrin kan lo sa deedee wo eka ile ifowopamo GTB kan ti a fi oruko bo ni asiri (tori aabo) ni ilu Eko , ti o si na ika owo re maraarun si awon osise ile ifowopamo naa ti o ba lori kanta , bi o ti se eyi tan lo ba bo si ori kanta ti o si bere si ni pale obiti biti owo iwaju awon osise naa mon sinu apo idoho nla ti o gbe lowo ,oju ese ni awon osise naa ba pe awon agbofinro ati awon olopa ti won wa ni ayika ile ifowopamo naa , nigba ti owo iya te okunrin naa lo ba bere si I ka boro boro pe oruka afeeri ti oun fi s'owo oun lo sise kise , o ni oun ro pe won ko ri oun ni ati pe ero oun ni pe oruka ti oun lo wa yo ti mu ki awon osise naa sun fon fon. Haaa , oruka afeeri oun ti se ise kise. Omo Nigeria nibo la n lo lori iwa ipa , ole ati ai fe kan an se wa , ojo gbogbo ni ti ole .....

Femi

OMO AKIN .......Yoruba lo so pe " Omo Ajanaku kii yara



Omo ti Ekun ba bi Ekun ni yo jo" asamo yi lo di'fa fun Ogagun Adeboye Obasanjo omo Yoruba atata ti o tun je Omo bibi inu Aare wa ana Oloye Olusegun Okikiola Obasanjo , eni ti o fara pa lopolopo loju ija nigba ti awon iko ti o n dari fija peeta pelu awon iko Boko Haram ni ijeta , Ninu oro re n'ile iwosan nibi ti o ti n gba itoju lo ti so fun awon oniroyin pe oun ti setan lati tun lo koju awon iko gbemi gbemi naa ti ara oun ba ti ya tan , o ni oun ko beru Boko Haram nitori pe ise ti oun gba ni lati mu ki Orile Ede Nigeria wa ni eyo kan soso , o tun tesiwaju pe koda oun ko ko ki emi oun bo sibe nitori pe eekan soso ni omokunrin maa n ku. Hummmm , nibi ti awon eya miran ti n sa seyin , ti won n y'odi seyin , Omo Aremu bee ni baba re maa n se , o kare , Olorun a maa ti o leyin , o ko ni gbe s'oju Ogun

Femi

Monday, September 8, 2014

Ori To Kẹ: Yoruba bọ, wọn ni ‘Oun gbogbo lọwọ ori


Edumare tun wa fi awọn nka mere-mere se ‘ẹsọ ori’
Bi oju, ahọn, eti, eyin ati ọpọlọ
Oju ni fitila ara, ahọn ni ọrọ, ọrọ nii yọ obi lápò, oun lo tun yọ ọfa lápó
Bi eti o ba gbọ yigin, inu kan o kin bajẹ,
Bẹẹ sini, bi eyin ba ti ka, ile ẹrin ti woo
Ti Yoruba ba sọ wipe ọpọlọ eyan ti jọba, ẹ ma fura si iru ẹni bẹ o.

ST