Showing posts with label Lo ba tan. Show all posts
Showing posts with label Lo ba tan. Show all posts

Tuesday, September 16, 2014

LO BA TAN: Kin lo le mu ki eniyan ri iku n'ile ki o si maa f'owo to o ni imu?


Kin lo le mu ki eniyan ri iku n'ile ki o si maa f'owo to o ni imu , bee gege ni oro okunrin ti e n wo yi ri ni adugbo Iju ni ilu Eko. Okunrin ti enikeni ko mo eye ti o su u yi ni won sa dee dee ba ti o ti gan mon ero amunawa , ibeere awon eniyan ni pe kin ni o wa de ibe sugbon igbagbo awon kan ni pe o seesee ki o je pe okunrin naa fe tu awon eroja ina kan lati lo taa a ni o fi ba iku re pade. Imoran ORO TO N LO ni pe ki a maa s'ora ooooo.
Femi

Friday, July 25, 2014

Lo ba tan, OWO TE OSIKA EDA !!!



Owo ma ti te e o , ni aye ijohun ni a maa n so pe awon obinrin ni oju aanu sugbon bayi,Opolopo won ni won daju ju ile agba lo. Ti e ko ba gbagbe ni ose die seyin la foju awon obinrin meta ti owo te pe won n ba awon iko Boko Haram sise po han lori eto yi,ase kekere la ri nigba naa,ni ijeta ojo'ru ni Obinrin miran tun ju ado Oloro nibi ti Dahiru Bauchi ti n se waasi , ori lo yo baba naa ti ko ba isele naa lo ni ilu Kaduna, Obinrin yi kaa naa lo tun saaju iko gbemi gbemi ti won tun kolu olori orile ede yi nigba kan ri , Ogagun Mohammadu Buhari ni ireti ati gbemi okunrin naa , sugbon ori ko ohun naa yo , abalo ababo ninu isele mejeeji ti obinrin yi ti ju bombu lojo naa lo ti ran Ogoji eniyan si orun apapa n dodo ti eniyan metadinlogosi si fara pa koja ala . Haaaaaa , Obinrin n gbase bombu jiju , awon naa ti n gbemi alaise .

ST