Monday, September 8, 2014

Ori To Kẹ: Yoruba bọ, wọn ni ‘Oun gbogbo lọwọ ori


Edumare tun wa fi awọn nka mere-mere se ‘ẹsọ ori’
Bi oju, ahọn, eti, eyin ati ọpọlọ
Oju ni fitila ara, ahọn ni ọrọ, ọrọ nii yọ obi lápò, oun lo tun yọ ọfa lápó
Bi eti o ba gbọ yigin, inu kan o kin bajẹ,
Bẹẹ sini, bi eyin ba ti ka, ile ẹrin ti woo
Ti Yoruba ba sọ wipe ọpọlọ eyan ti jọba, ẹ ma fura si iru ẹni bẹ o.

Yoruba a gbe oriyin fun Ori…’Oritookẹ! Ori ẹni lapesin,
Oun lawure ẹni, Ori lẹja fi n labu, Ori lawọn wọnbiliki tun fi n mẹran lawo.
Oun kanna ni obilẹjẹ eyan fi n pa kadara ẹni da.
E̩ ma kẹ ori yin ni o, bi Ijapa se n kẹ ti ẹ, Ijapa se ori bintin, o wa se ẹ̀yìn gannanku
Bi ẹ̀yìn Ijapa se tobi to, bẹẹni ọgbọn rẹ na se tobi to
Sugbọn, gbogbo ọgbọn Ijapa, inu ori bintin ni Eledumare kosi
Ijapa wa n fi ẹ̀yìn gannaku se itọju Ori bintin, Bi Ijapa ba ko firi aburu, a gbe ori pamọ sinu ẹyin gannanku
Bo ba n rẹju lasan, inu ẹyin gannanku ni ori Ijapa n pamọ si
Iwọ aunti Oritookẹ ati iwọ bọọda Orimoogunjẹ,
Kikẹ lori, gbogbo yin ẹ ma kẹ ori yin ni o.
Ori ẹni lakunlẹyan, oun na ladayewaba.
Ibi tẹsẹ ngbe ni re, ori lo mọ bẹ o
Emi nlọ na o, bori ba bami se, mo tun pada bọ
===============================
Ibi Orimi Aati Sanre, Ki E̩sẹ Mi Ma Saa Lai Gbe Mi Rebẹ

No comments:

Post a Comment

ST