Friday, September 26, 2014

Ko Se Duro Wo !


Ko se duro wo, bo se nlọ la ntẹle…ohun awọn ọmọ igboro ni
Ko kuku si irọ nbẹ, Yoruba gan sọ wipe ‘atatọ ni’, bo ba se nta, ni ko ma tẹle
ọdẹ k’ọdẹ to ba ta, ti o tẹle, iru ẹran bẹẹ loun d’ẹran idin
Iwọ kawe gboye rẹpẹtẹ, ori ‘what will be will be’ lo duro le,

O wa n yunra isẹ ni sise, a ni o bẹrẹ lati ibikan, ‘O ti di ‘football analyst’ la’dugbo
‘Ti a ba fi le gba draw pẹlu Barca ninu ile wọn, apa awọn ọmọ Chelsea a jabọ ni’
Ranti o, ori ‘What will be will be’ yi ni Nigeria duro le lati 1914’
Ti ko pada wa bi nkankan fun wọn
ẹlomi a bimọ dalẹ bi eku ẹda, wọn bi leere…
Awọn nkan wo loun se silẹ de ọmọ? Alakọri sọ wipe ‘ọlọhun ni wo ọmọ Weere’
ọrọ rẹ mu mi ranti Weere ọlọmọ kan ni ilu osogbo oroki
Ayegbajẹjẹ lookọ rẹ njẹ, ko si nkan tẹ fun ti o fun ọmọ jẹ
Awọn ijọba wo sunsun, wọn ni, ‘ B’isin o ba la, se bi ọmọ inu rẹ o la
Ijọba petepero, wọn da bi ogbọn, wọn gbe kalẹ bi ete
Wọn yọ ọmọ lẹyin ayegbajẹjẹ, ayegbajẹjẹ tutọ s'oke, o f'oju gba
Kai !! ta lo nba wọn d’asa ‘ ko si iya weere ?
Awọn ijọba o le duro wo, ayegbajeje gan ntẹle wọn
Gbogbo eyan sa kabakabakaba, igba yẹn lo to ye mi wipe
Weere se abiamọ ju ọmọ ẹlomi lọ
Lati ọwọ: Raymond Ajeigbe

No comments:

Post a Comment

ST