Friday, May 23, 2014

O MA SE OOO: kin lo fa iku arabinrin Mary Paul ?



O MA SE OOO:- Ti eniyan ba je ori ahun ti o ba de Chibock l'oni yo sunkunn , nibi ti awon ara adugbo naa ti n ba idile alagba Paul kedun iyawo re ti o file saso bora . Lana ni arabinrin Mary aya Paul ki aye pe o digbose , kin lo fa iku arabinrin Mary Paul ? Won ni eje riru lo pa arabinrin naa nitori pe omo re meji lo wa ninu awon omo ti o wa ni igbekun Boko Haram, nigba ti ireti re pin lori riri awon omo naa lo ba bere si I ru lo n gbe tori pe ojoojumo ni eje re n ru titi ti o fi ku lana. O ma se oooooo

Femi

NNKAN N BE. Ni ojo'ru ose yi ni isele nla kan sele ni agbegbe Ajegunle ni ilu Eko

  Gege bi ogbeni Okafor ti isele naa soju re se so,o ni sadeede ni eye kan sadeede ja lule lati oju ofurufu,ka to fo ka to wi eye naa ti yira pada ti o si di iya arugbo kan,loju ese ni gbogbo awon to wa nibe sa seyin,leyin iseju die won sunmo iya arugbo naa ti o si so pe aje ni oun ati pe meta ni awon,ise buruku kan ni awon wa se ni Eko ki ile to mon ba awon,nibi ti oun ti n fo kiri lai mona mo loun se ja lule.

Femi.

Thursday, May 22, 2014

OKUNRIN TO SO ARA RE DI OBINRIN TI DARA SI O


 Nigba ti a gbe iroyin yi ni bi osu mefa seyin opo eniyan ni won pe wa ni opuro nigba naa,bi o tile je pe o soro lati gbabo looto sibe otito ni a so nigba naa. Ni bayi o , o ti wa daju gbangba si gbogbo agbaye pe okunrin ni Omidan Sahara tele ki o to so ara re di obinrin apapa n dodo. Oruko ti iya ati baba re so o ni Oche Clifford , okunrin ni won bi i , University Benue lo lo laarin odun 2000-2013. Gbara ti o kuro ni University naa lo to poro bo si ilu Oba (UK) nibe ni o ti yan ise asaraloge laayo ti o si ri pe Obinrin lo po ninu awon onibara oun julo , ati pe ko si obinrin ti yoo maa se ara loge lodo okunrin ni Clifford naa ba ta a bi ogbon lati so ara re di obinrin , won bere ise abe fun un , Olorun si gbo adura re ise abe naa yori si daadaa , lati igba naa lo ti di obinrin. Inu mi wa dun pe opo to pe wa ni opuro nigba naa ni won ti tun wa n kan saara si wa bayi pe a kii mu amulu mala. E se e ooooo


Femi

Wednesday, May 21, 2014

Aja to R'ele Ekun To bo


 Aja to r'ele Ekun to bo , ka ki I ku ewu ni o , bee ni oro Omobinrin yi Godiya Simon eni ti o wa lara awon omo ile iwe Chibok ti awon Boko haram ji ko.Ninu oro re Godiya ni bi ose meji ti oun fi wa nibe , inu igbo kijikiji ni won ko awon si pelu iberu ati ifoya ni awon si fi wa nibe ki Olorun to wa ko oun yo nigba ti oun paro pe oun fe lo to,ti oun si sa mon won lowo,o ni leyin irin ojo meji gbako ninu igbo naa loun to pade awon Fulani ti o mu oun jade si gbangba

Femi Ojewale

Tuesday, May 20, 2014

KIM K ATI KANYE WEST FE SE IGBEYAWO

Gege bi iroyin to n te wa lowo bayi ni pe,Omobinrin ti o maa n fi Oyan ati idi re ya foto fun awon ile ise ti won ba fe irufe aworan bee ma ti so pe o to gee bayi o,Ninu oro re Kim Kardashian ni oun ko fe fi foto ihooho oun han araye mo.O ni oko oun Kanye West ti o je omo ile America nikan ni o ku ti yoo maa ri ihooho oun bayi o,Kim soro yi nibi igbaradi ayeye igbeyawo re ni ilu France , gbogbo eyin ti e ti ni aworan tabi fidio ihooho Kim nile tele,oun ko lo wa nibe mon oooooooooooooo


Femi Ojewale

Monday, May 19, 2014

T'ORI OLORUN: Adajo kan ni Orile Ede Sudan ni ki won lo yegi fun abileko kan titi emi yo fi bo ni ara re



 N se ni igbe ekun n ta l'otun ati l'osi ni ojo'bo ose ti o koja nigba ti adajo kan ni Orile Ede Sudan ni ki won lo yegi fun abileko kan titi emi yo fi bo ni ara re. Meriam Yahaya Ibrahim , eni odun metadinlogbon ti o loyun sinu ti o ti bimo kan fun oko re yi tele ni won so pe o d'ese nla nitoripe o se igbeyawo pelu omo leyin Kristeni , idi niyi ti won fi ni ki won lo yegi fun un. Huuuummmmm o ga ooo !!!


Onirohin ọkunrin -- Femi Ojewale‎

Sunday, May 18, 2014

Eemo W'olu ooo: ni ilu Ilobu ni ijoba ibile Irepodun ni Ipinle Osun


Laaro ojo'bo ninu ose ti o koja ti awon ara ilu Ilobu ni ijoba ibile Irepodun ni Ipinle Osun ji,n se ni gbogbo olugbe ilu naa n ko ha ha ha nitori pe enu ya won si oun ti o sele naa. N se ni won ba odomokunrin eni ogun odun ti oruko re n je Abdullahi omo ile Tooto ninu ilu naa ti o ti ku si eti saare nibi ti o ti fe ji oku kan ti won sese sin wu,o ti ori bo inu isa oku naa lati faa jade ni oun naa ko ba le jade mo titi o fi ku sibe.Tabi e ko ri nnkan bi ?


Femi Ojewale‎

Omi Tan Leyin Eja Won: owo awon omo ogun JTF te Mejo ninu awon gbemi gbemi Boko Haram

OMI TAN LEYIN EJA WON. Mejo ninu awon iko gbemi gbemi Boko Haram miran ni owo awon omo ogun JTF Nigeria ma tun ti te bayi ni abule Goym ni ijoba ibile Dikwa ni ipinle Borno nibi ti won ti jade wa pelu oko akero Hilux pelu keke alupupu meji lati wa ra onje ati aso . Gege bi arigbamu iroyin ti a gbo lati Olu famous ni pe awon mejo yi ti jewo pe awon omo ile iwe ti won ji ko lojosi wa ninu igbo Sambisa , awon ti owo te naa ti jewo ibi ti awon die wa , eyi lo tun mu ki owo te opolopo won.

Femi Ojewale‎

Owo Palaba S'egi: Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram



Ko din ni Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram ti won bo sowo ibon awon apapo omo ogun JTF ti orile ede yi. Ninu ija naa ti o gbona jan jan ninu igbo ti won n pe ni igbo Lamba , ni ijoba ibile Gwaram ni ipinle Jigawa ni ibon awon soja naa ti gbemi Ogota awon Boko Haram ti gbogbo ileto ti o wa ni agbegbe naa si kan gbinrin gbinrin nigba ti won n gburo ibon lotun losi . Ki Olorun tubo maa d'abo re bo wa oooooo


Femi Ojewale

Wednesday, May 14, 2014

Itan Egungun Ni Ile Yoruba

Egungun je Orisa pataki kan nile Yoruba nigba lailai, sugbon kiise Orisa ile Yoruba rara idi niyi ti enikan ko fi le so oruko eni to da sile bi ti awon Orisa toku bi Sango, Ogun, Oya ati bebe lo. Iwadi miran ni igbagbo lori pe ara orun ni Egungun ni ko je ki won le wa fi oruko eni to da sile ti si ara enia to je ara aye ki awo Egungun mo lo ya. Sugbon loni pupo ninu awon to ngbe Egungun gan ko mo awo Egungun tabi itan bi Egungun se bere gan, bi ose bere ni idile onikaluku nikan lo mo.

Monday, May 12, 2014

Excellent Yorùbá Choral Piece

Friday, May 9, 2014

IKIRE: Eledumare o ma jeki asirin ( gbomo gbomo)

IKIRE...... Hmmmm, eyin ti enmun gbomo gbomo ema kie sara nitori irin ese elomiran manparo mon ki Eledumare o ma jeki asirin, agbo wipe eni ti won mun gege bibi gbomo gbomo ni kise gbomo gbomo ti awon monlebi re si ti nfi OLOPA (POLICE) ko gbogbo awon aladugbo Sanngo mon opopona ile iwosan ijoba ibile, eyin ti eba ni olode ori etete lo toju won ki won o ma kawon kun gbomo gbomo, iwo ti o ba nrin irin ajo ti oosi mon adugbo ibi ti ounlo kiesara daadaa ki won ma kero wipe gbomo gbomo nie Eledumare koni jeki a sirin Oooooo

Adigun Olori Odo‎

Tuesday, May 6, 2014

Gbomo ni GARAJI ODEYINKA

IKIRE latun wao, ago mi dun ganranran ti mosi gbo wipe won n danasun gbomo gbomo kan ni SANNGO nilu IKIRE lowo lowo, oti jona ti awon eniyan si ti tuka lori re kato debe, enikan tun sare de janajanan wipe won tun ti mun gbomo gbomo miran ni GARAJI ODEYINKA ni AKO nilu IKIRE bakanan, Ogao asiri yin kobo mon,  OLORUN AGBAWA LOWO GBOMO GBOMO ASA AYE KO NI KO WA LOMO LO O00000( ASE 0000000)

E Gbo Naa kinni O maa N'fa Tii Awon Okunrin Kan Maa N'ba Osise Tabi Omo - Odo Iyawo Won Seere Ife???


Eyin Ore Mi, E Gbo Naa kinni O maa N'fa Tii Awon Okunrin Kan Maa N'ba Osise Tabi Omo - Odo Iyawo Won Seere Ife???

Saturday, May 3, 2014

Yoruba sọ wipe: ORUKỌ RERE…...

Yoruba sọ wipe…. o san ju wura ati fadaka lọ
Igbẹ kinkin leti awo gbẹgiri, wọn ka mu kuro kama jẹun lọ
bo’ju ba kuro nbẹ, s'ọkan le kuro nbẹ ni
Orukọ-rere pẹlu owo-nini, orẹ mi, o gba lakaye o
Bi wọn bani o ma ko gbogbo ẹ nmeji -meji
iwọ sọ wipe o ti gbọ, dakun ma jẹ awọn ara ọyọ o tiọ ntikuti o
Yoruba to sọ wipe ko f’oko kan p’ẹyẹ meji
awon nọni wọn tun sọ pe booba leku meji, o pofo kan
gbogbo, isha ni !… isha lẹwon! a tilọ, a tide

ST