Showing posts with label TI DARA SI O. Show all posts
Showing posts with label TI DARA SI O. Show all posts

Thursday, May 22, 2014

OKUNRIN TO SO ARA RE DI OBINRIN TI DARA SI O


 Nigba ti a gbe iroyin yi ni bi osu mefa seyin opo eniyan ni won pe wa ni opuro nigba naa,bi o tile je pe o soro lati gbabo looto sibe otito ni a so nigba naa. Ni bayi o , o ti wa daju gbangba si gbogbo agbaye pe okunrin ni Omidan Sahara tele ki o to so ara re di obinrin apapa n dodo. Oruko ti iya ati baba re so o ni Oche Clifford , okunrin ni won bi i , University Benue lo lo laarin odun 2000-2013. Gbara ti o kuro ni University naa lo to poro bo si ilu Oba (UK) nibe ni o ti yan ise asaraloge laayo ti o si ri pe Obinrin lo po ninu awon onibara oun julo , ati pe ko si obinrin ti yoo maa se ara loge lodo okunrin ni Clifford naa ba ta a bi ogbon lati so ara re di obinrin , won bere ise abe fun un , Olorun si gbo adura re ise abe naa yori si daadaa , lati igba naa lo ti di obinrin. Inu mi wa dun pe opo to pe wa ni opuro nigba naa ni won ti tun wa n kan saara si wa bayi pe a kii mu amulu mala. E se e ooooo


Femi

ST