Wednesday, May 14, 2014

Itan Egungun Ni Ile Yoruba

Egungun je Orisa pataki kan nile Yoruba nigba lailai, sugbon kiise Orisa ile Yoruba rara idi niyi ti enikan ko fi le so oruko eni to da sile bi ti awon Orisa toku bi Sango, Ogun, Oya ati bebe lo. Iwadi miran ni igbagbo lori pe ara orun ni Egungun ni ko je ki won le wa fi oruko eni to da sile ti si ara enia to je ara aye ki awo Egungun mo lo ya. Sugbon loni pupo ninu awon to ngbe Egungun gan ko mo awo Egungun tabi itan bi Egungun se bere gan, bi ose bere ni idile onikaluku nikan lo mo.


Awon Tapa loni awo Egungun idi niyi ti won ba ki Egungun won gbodo ki mo Tapa ni aye atijo. Opo waala ni awon Oba Alafin se ki won to le mo awo Egungun lodo awon ara Tapa opo emi lo si sona pelu nitori opo alami ti won ba ran lo ni ki I bo, ohun ti awon Tapa si mo nso ni pe orun ni awon Egungun ti mo wa be awon wo, awa naa yio ri pe awon Tapa naa lo ni Orisa Igunnuko ti ohun ati Egungun fe jo ara won. Bi Alafin Sango se je omo Tapa nidi iya to won o fi awo Egungun han.

Gbogbo igba ti awon Tapa ba si gbe ogun ti Yoruba tawon ti Egungun ni iberu pe ara orun ni nba awon ja si mo nje ki awon Tapa segun. Sugbon nigbati ogun Tapa tu Oyo Alafin laye Oba Onigbogi ti won si sa lo ile Ibariba nile Ibariba ni Alafin Ofinran ti se aseyori nipa riri asiri awo Egungun lodo awon Tapa, ti won wa mo pe enia lo nbe labe oro ti oro nfi ke, Alafin Ofinran pa asiri yi mo, oun si naa si pase ki won gbe Egungun jade, eru Oba to ri asiri yi ni nje Saha nibi oke kan to nje Oke Sanda ni asiri ti ya si lowo nitori o fi emi e lele pe dandan se oun gbodo ri asiri Egungun.

Nigbati ogun nlo lowo larin Yoruba ati Tapa Saha ko kopa ninu ogun rara awon Egungun lo nso titi to fi ri aye sa de ibi Oke Sanda fun odidi osu meji si meta lo fi nso won to mo asiri won dada bayi lo se gbe Eku kan ninu Eku Egungun awon Tapa to si wo pada si ago awon Yoruba nigbati won ri oni ki won mo sa o atipe ohun wa lati orun ni pelu pe Alafin Ofinran lohun fe se lore, kia won mu lo odo Alafin Ofinran nigbati o ku awon Oyo Mesi lodo Oba tan Saha bo ago sile o si fi awo Egungun han Alafin Ofinran, bayi ni Alafin ni ki awo Egungun je eyi to pa mo fun awon agbagba nikan atipe ti awon omo ogun ba ri pe Egungun ti orun wa sodo awon naa bi ti awon Tapa won yio ni okun ati se awon Tapa logun. Kia won ti da Eku Egungun bi igba Saha si lewaju awon Egungun to lo ogun bayi ni won se segun awon Tapa.


Nigbati awon Tapa ri pe Yoruba ti mo awo Egungun tan ki Yoruba mo wa tu awo yi ki awon omo Tapa ti awon Oba won ti mo nso fun pe ara orun ni Egungun mo wa lo mo awo, won ba Yoruba di awo pelu adeun pe awon o tun je gbe ogun wo ile Yoruba mo won wa fi awon ti yio wa ko Yoruba awo Egungun ranse si Alafin Ofinran, oruko awon ti won fi ranse naa niyi Elefi, Olohan, Oloba, Aladafa, Oloje. Bi egungun se di orisa nile Yoruba niyi ti ilu kokan naa si ni Egungun tiwon pelu iyoda Alafin, enu ko ko boya Saha ni Alapini akoko

No comments:

Post a Comment

ST