Igbẹ kinkin leti awo gbẹgiri, wọn ka mu kuro kama jẹun lọ
bo’ju ba kuro nbẹ, s'ọkan le kuro nbẹ ni
Orukọ-rere pẹlu owo-nini, orẹ mi, o gba lakaye o
Bi wọn bani o ma ko gbogbo ẹ nmeji -meji
iwọ sọ wipe o ti gbọ, dakun ma jẹ awọn ara ọyọ o tiọ ntikuti o
Yoruba to sọ wipe ko f’oko kan p’ẹyẹ meji
awon nọni wọn tun sọ pe booba leku meji, o pofo kan
gbogbo, isha ni !… isha lẹwon! a tilọ, a tide
Iwọ lo t’ẹwọn de, orukọ rẹ o t’ẹwọn de o, walahi, digbi l’orukọ rẹ duro sọun
Iwọ ni suru jẹ ki wọn o beere rẹ lọwọ aunti dalemosu adugbo yin
A un beere bọọda lagbaja? o ma gbọ..’ bọọda ewo nbẹ?
se bọọda ile ọkan abi eyi to sẹsẹ t'ẹwọn de
ọwọ ọlọpa tẹ ọmọ alagidi adugbo wa ni ọjọ kan
Awọn eyan sọ wipe, ẹ filẹ, ẹ jẹ ko lọ s'ẹwọn lọ kọ'gbọn
ọrẹ lọ ẹwọn, o kọ'gbọn o pada de o, njẹ ko darapọ mọwa
Yooba tun ni,,,ẹjẹ ka ma yẹra fun o, gbogbo wa lamọ wipe o ti lọ ẹwọn ri
Alagẹmọ toun yọ’lẹ tẹ, iku npa, abele tase ọpọlọ to njan ara rẹ mọlẹ
Ni'rọlẹ ijọkan, a ni mo beere ọrẹ mi abuke (hunch-back man) kan ladugbo wọn
wọn ni se bọọda t’ẹyin ndun
ma se jẹjẹ o, ki ọrọ rẹ ma lọ dabi afọwọfọnna ti ki m’ọwọ duro.
No comments:
Post a Comment