Saturday, May 3, 2014

Yoruba sọ wipe: ORUKỌ RERE…...

Yoruba sọ wipe…. o san ju wura ati fadaka lọ
Igbẹ kinkin leti awo gbẹgiri, wọn ka mu kuro kama jẹun lọ
bo’ju ba kuro nbẹ, s'ọkan le kuro nbẹ ni
Orukọ-rere pẹlu owo-nini, orẹ mi, o gba lakaye o
Bi wọn bani o ma ko gbogbo ẹ nmeji -meji
iwọ sọ wipe o ti gbọ, dakun ma jẹ awọn ara ọyọ o tiọ ntikuti o
Yoruba to sọ wipe ko f’oko kan p’ẹyẹ meji
awon nọni wọn tun sọ pe booba leku meji, o pofo kan
gbogbo, isha ni !… isha lẹwon! a tilọ, a tide

Wednesday, April 30, 2014

Ori To Kẹ Yoruba bọ, wọn ni ‘Oun gbogbo lọwọ ori ni’.


Edumare tun wa fi awọn nka mere-mere se ‘ẹsọ ori’
Bi oju, ahọn, eti, eyin ati ọpọlọ
Oju ni fitila ara, ahọn ni ọrọ, ọrọ nii yọ obi lápò, oun lo tun yọ ọfa lápó
Bi eti o ba gbọ yigin, inu kan o kin bajẹ,
Bẹẹ sini, bi eyin ba ti ka, ile ẹrin ti woo
Ti Yoruba ba sọ wipe ọpọlọ eyan ti jọba, ẹ ma fura si iru ẹni bẹ o.
Yoruba a gbe oriyin fun Ori…’Oritookẹ! Ori ẹni lapesin,

Monday, April 28, 2014

EJA N'BAKAN: Itan Eja Ni Abi Akan

AKAN ati EJA je pataki ninu awon opolopo omo Yeyemoja Olokun. Ni ojo kan ni Yeyemoja pe omo re EJA-(fish) pe ki o lo ba ohun sin gbese. Nigbati Eja-(fish) de odo onigbese, ni o ba (tu ito soke, lo fi oju gbaa). Ni o baraje, O soro abuku ohun ete si oni-gbese.
Iwa ibaje yii, mu ki inu bi onigbese, o pinu pe ohun ko ni gbesee kan san. Eja(fish) kori sile, ko ri gbese naa gba, o rele pelu ofo; ojo-keji oja.

Saturday, April 26, 2014

Ekú déédé ìwòyí o! - Ìbéèrè mi nì

Ekú déédé ìwòyí o!
Èyin èèyàn mi lórí ètò yí, ejòwó ebámi dásí òrò yí, bí àwon baba wa nílè yorùbá báfé júbà won a máa so báyìí pé;
ÌBÀ AKÓDÁ, ÌBÀ ASÈDÁ, ÌBÀ ÀTIWÁSÁYÉ. Ìbéèrè mi nìní; tani akódá?
Tani Asèdá?
Kíni àtiwásáyé?

Thursday, April 24, 2014

ERIN WO. Erin wo, Ajanaku sun bi oke.


 Eyin ka ile erin ti wo , Afemojo ku enu isa n s'ofo............................. Lana ojo ketalelogun , osu Kerin ni iku wole to mu Alhaji Moshood Ayinde (Olorun Esan ) lo. Ojulowo onisowo ,omo Apomu, lo nile yi ao ri o mon , Parakoyi oloselu o digba o, ilu London niku ti pa baba ni eni odun metalelaadorin (73 years). Baba Biola o digba .Iba se pe a ki ku laye , Olorun Esan a ba so pe iku jare re....



Femi Ojewale

ASIRI TU: ni adugbo Aperin ni ilu lbadan


 Laipe yi ni owo te obinrin kan ni adugbo Aperin ni ilu lbadan , nigba ti owo awon Olopa ti o n dagbo mo awon ti won n fi omo s'owo eru te Hellen ati oko re ogbeni Temitope lori esun pe won n fi awon omo k'ogbo k'ogbo ti won ko ti I to omo odun mejidinlogun se ise Asewo . Mo gbe osuba bamba fun Komisana ati awon Olopa ilu Ibadan fun aseyori ise naa. E ku ise o


Femi Ojewale

NNKAN N BE. Ireti obi ni pe ki obi jere omo l'ojo ale


Ireti obi ni pe ki obi jere omo l'ojo ale.Sugbon ni ti Elizabeth ko ma ri bee o, Looto,o lo s'ile iwe alakobere,o lo si girama leyin naa lo wole s'ile iwe Obafemi Awolowo Yunifasiti,lle lfe nibi ti o ti n ko ise imo isegun Oyinbo.o ku bi osu meta pere ki o pari eko re ni awon osika eda kan lo fi tipa tikuuku ba a sun ti won si tun pa a, gege bi a se gbo,won ni omo jeje ni Elizabeth ki o to di pe won da emi re legbodo ti won si yo awon nkan kan lo lara re



Femi Ojewale

ST