Monday, July 28, 2014

KIN LO DE ? Isele Ni deedee agogo meji osan

 Ni deedee agogo meji osan yi ni Obinrin kan sa deedee yo sibi ti awon olopa ti n seeto lati ko awon oku ti bombu pa laaro yi kuro nile ni ile Epo nla Hotoro ni ilu Kano. Bi obinrin eleha naa se de agbegbe naa ni awon agbofinro ti o wa nibe ti n fura si I , loju ese lo ba mori le ona ibudo ipate oja (Kano Trade fair Complex) nibi ti Ogunlogo awon olopa wa , ninu akiyesi awon olopa , won ri pe ara Obinrin naa ko bale ati pe o ro kini kan mo aso ibori re ti awon Musulumi n pe ni Hijab , loju ese ni awon Olopa ba sun mo on , nibi ti won ti n fi oro wa a lenu wo ni ado oloro (bomb) ti o gbe sara ti dun lojiji ti o si ja obinrin naa jaka jaka , bakan naa lo se awon Olopa merin ti o sunmo on lese lopolopo. E jowo e ma dake adura ooo , ti e ko ba gbagbe obinrin kan ti koko ju bombu sile epo Hotoro ni Kano laaro yi .

No comments:

Post a Comment

ST