Ni aye atijọ Apẹrẹ ati Ikoko jẹ ọrẹ timotimo
koda o l'oju ẹni tole ri aarin wọn. L'ọjọ kan
ni Ikoko gbera o di ọdọ Apẹrẹ nigbati o de
bẹ wọn ki ara wọn gegebi ọrẹ atata, laipẹ
ni omoge awelewa kan nbọ ti osi da ede
ayede sile laarin wọn.
Apẹrẹ: Ikoko, wo omobinrin to nbọ yi o
wu mi gidigidi mosi fẹ fi s'aya.
Ikoko: Apẹrẹ, kilo ma n se ẹ na, se o ri
wipe emi lo n wo ni? Ọrọ na da aawọ sile
laarin awọn mejeeji ti omobinrin na fi sọ
wipe oun fẹ mọ eni t'oni agbara ju ninu
awọn mejeeji. O ni oun fẹ mu omi wipe
omi ojo l'oun si fẹ tio si jẹ wipe ojo n rọ
lọwọ, kia Ikoko ti bọ sinu omi o gbe om
funi omoge na inu ọmọ naa si dun gidigidi
sugbon Apẹrẹ kori omi bu wa, ni Ikoko ba
beresi ni fi Apẹrẹ se yeye wipe kole ba ojo
da; inu Apẹrẹ bajẹ gidigidi o si gbadura si
Ọlọrun. K'ato wi k'ato fọ, omobinrin yi tun
ti n pariwo ebi, o ni oun yio gbe wọn losi
oko lati lọ fi okookan wọn wa ounjẹ; wọn
si gba bẹẹ. Ikoko lo kọkọ gbe lọ si oko
sugbon nigbati o n pada bọ wa sile nkan
kọ omobinrin na l'ẹsẹ o subu Ikoko na si
fọ yangayanga, loba sare lọ gbe Apẹrẹ na
ni'le o fi ko iṣu na wale o tun subu l'oju
ona ṣugbọn kosi ohun to se Apẹrẹ. Loba
pinnu lati fi Apẹrẹ se ade ori rẹ nitori wipe
akikanju eniyan ni Apẹrẹ.
Ẹyin ara wa, ẹ jọ, Ẹkọ wo lẹ ro pe itan yi kọ wa ??:
No comments:
Post a Comment