Sunday, June 15, 2014
KINI KI A PE EYI O !!! Se efun ni ki a pe e ni tabi eedi
OWO TI TE WON O !!! Owo te Meta ninu awon omo iko gbemi gbemi Boko Haram ni ojo eti
Meta ninu awon omo iko gbemi gbemi Boko Haram ti won pa opolopo eniyan laipe yi ni Ijoba Ibile Gwoza ni iko JTF ti te ni ijeta ojo eti , enikan ti awon iko naa du egbon re bi eni du eran lo da okan mo ninu keke Maruwa ti won jo wo , oju ese ni o figbe ta pe oun mo okunrin ti o joko ti oun gege bi okan ninu awon omo iko Boko Haram nigba ti owo iya ba a daadaa lohun naa ba naka si awon meji miran pe ara kan ni awon , loju ese ni won si fa won le olopa lowo .
Femi
Sunday, June 1, 2014
Ohun Buruku Ni Ko Taka Sori
Nibi ti omo Yoruba bawa, tI aba ri eni so oro buruku tabi oro odi, awon omo Yoruba ti oba wa ni be ma taka l'emeta ni kiakia, won a tuni 'Olorun maje'. Iye tumosi pe, oro buruku yen ti fowo n da.
Ohun lodifa fun mama Ajala to ntata ni ita katakara. Tiwon soro odi legbe e, ti ko tete taka danu, atanpako e di talantolo, lojo keji, o gbo ohun eye Ibaka to nso 'Ohun buruku ni ko taka sori' Mama Ajala yara fi ata re sile o lo fo ori e nu ni odo to nso legbe ile Alara to nta taba loja Afariga. Won bi mama Ajala lere wipe kilode to nfi fori nu, o nihun ti eye ri ti ofi ni kohun taka, nigba tohun o teteri eni tasi, lohun ya lo fori nu s'odo to nso.Nitori idi eyi, e maje ki won taka le yin lori o
"E ya yara taka osi danu"
Friday, May 23, 2014
O MA SE OOO: kin lo fa iku arabinrin Mary Paul ?
Femi
NNKAN N BE. Ni ojo'ru ose yi ni isele nla kan sele ni agbegbe Ajegunle ni ilu Eko
Femi.
Thursday, May 22, 2014
OKUNRIN TO SO ARA RE DI OBINRIN TI DARA SI O
Nigba ti a gbe iroyin yi ni bi osu mefa seyin opo eniyan ni won pe wa ni opuro nigba naa,bi o tile je pe o soro lati gbabo looto sibe otito ni a so nigba naa. Ni bayi o , o ti wa daju gbangba si gbogbo agbaye pe okunrin ni Omidan Sahara tele ki o to so ara re di obinrin apapa n dodo. Oruko ti iya ati baba re so o ni Oche Clifford , okunrin ni won bi i , University Benue lo lo laarin odun 2000-2013. Gbara ti o kuro ni University naa lo to poro bo si ilu Oba (UK) nibe ni o ti yan ise asaraloge laayo ti o si ri pe Obinrin lo po ninu awon onibara oun julo , ati pe ko si obinrin ti yoo maa se ara loge lodo okunrin ni Clifford naa ba ta a bi ogbon lati so ara re di obinrin , won bere ise abe fun un , Olorun si gbo adura re ise abe naa yori si daadaa , lati igba naa lo ti di obinrin. Inu mi wa dun pe opo to pe wa ni opuro nigba naa ni won ti tun wa n kan saara si wa bayi pe a kii mu amulu mala. E se e ooooo
Femi
Wednesday, May 21, 2014
Aja to R'ele Ekun To bo
Aja to r'ele Ekun to bo , ka ki I ku ewu ni o , bee ni oro Omobinrin yi Godiya Simon eni ti o wa lara awon omo ile iwe Chibok ti awon Boko haram ji ko.Ninu oro re Godiya ni bi ose meji ti oun fi wa nibe , inu igbo kijikiji ni won ko awon si pelu iberu ati ifoya ni awon si fi wa nibe ki Olorun to wa ko oun yo nigba ti oun paro pe oun fe lo to,ti oun si sa mon won lowo,o ni leyin irin ojo meji gbako ninu igbo naa loun to pade awon Fulani ti o mu oun jade si gbangba
Femi Ojewale
Subscribe to:
Posts (Atom)