Femi.
Friday, May 23, 2014
NNKAN N BE. Ni ojo'ru ose yi ni isele nla kan sele ni agbegbe Ajegunle ni ilu Eko
Femi.
Thursday, May 22, 2014
OKUNRIN TO SO ARA RE DI OBINRIN TI DARA SI O
Nigba ti a gbe iroyin yi ni bi osu mefa seyin opo eniyan ni won pe wa ni opuro nigba naa,bi o tile je pe o soro lati gbabo looto sibe otito ni a so nigba naa. Ni bayi o , o ti wa daju gbangba si gbogbo agbaye pe okunrin ni Omidan Sahara tele ki o to so ara re di obinrin apapa n dodo. Oruko ti iya ati baba re so o ni Oche Clifford , okunrin ni won bi i , University Benue lo lo laarin odun 2000-2013. Gbara ti o kuro ni University naa lo to poro bo si ilu Oba (UK) nibe ni o ti yan ise asaraloge laayo ti o si ri pe Obinrin lo po ninu awon onibara oun julo , ati pe ko si obinrin ti yoo maa se ara loge lodo okunrin ni Clifford naa ba ta a bi ogbon lati so ara re di obinrin , won bere ise abe fun un , Olorun si gbo adura re ise abe naa yori si daadaa , lati igba naa lo ti di obinrin. Inu mi wa dun pe opo to pe wa ni opuro nigba naa ni won ti tun wa n kan saara si wa bayi pe a kii mu amulu mala. E se e ooooo
Femi
Wednesday, May 21, 2014
Aja to R'ele Ekun To bo
Aja to r'ele Ekun to bo , ka ki I ku ewu ni o , bee ni oro Omobinrin yi Godiya Simon eni ti o wa lara awon omo ile iwe Chibok ti awon Boko haram ji ko.Ninu oro re Godiya ni bi ose meji ti oun fi wa nibe , inu igbo kijikiji ni won ko awon si pelu iberu ati ifoya ni awon si fi wa nibe ki Olorun to wa ko oun yo nigba ti oun paro pe oun fe lo to,ti oun si sa mon won lowo,o ni leyin irin ojo meji gbako ninu igbo naa loun to pade awon Fulani ti o mu oun jade si gbangba
Femi Ojewale
Tuesday, May 20, 2014
KIM K ATI KANYE WEST FE SE IGBEYAWO
Femi Ojewale
Monday, May 19, 2014
T'ORI OLORUN: Adajo kan ni Orile Ede Sudan ni ki won lo yegi fun abileko kan titi emi yo fi bo ni ara re
Onirohin ọkunrin -- Femi Ojewale
Sunday, May 18, 2014
Eemo W'olu ooo: ni ilu Ilobu ni ijoba ibile Irepodun ni Ipinle Osun
Laaro ojo'bo ninu ose ti o koja ti awon ara ilu Ilobu ni ijoba ibile Irepodun ni Ipinle Osun ji,n se ni gbogbo olugbe ilu naa n ko ha ha ha nitori pe enu ya won si oun ti o sele naa. N se ni won ba odomokunrin eni ogun odun ti oruko re n je Abdullahi omo ile Tooto ninu ilu naa ti o ti ku si eti saare nibi ti o ti fe ji oku kan ti won sese sin wu,o ti ori bo inu isa oku naa lati faa jade ni oun naa ko ba le jade mo titi o fi ku sibe.Tabi e ko ri nnkan bi ?
Femi Ojewale
Omi Tan Leyin Eja Won: owo awon omo ogun JTF te Mejo ninu awon gbemi gbemi Boko Haram
Femi Ojewale
Subscribe to:
Posts (Atom)