Tuesday, May 20, 2014

KIM K ATI KANYE WEST FE SE IGBEYAWO

Gege bi iroyin to n te wa lowo bayi ni pe,Omobinrin ti o maa n fi Oyan ati idi re ya foto fun awon ile ise ti won ba fe irufe aworan bee ma ti so pe o to gee bayi o,Ninu oro re Kim Kardashian ni oun ko fe fi foto ihooho oun han araye mo.O ni oko oun Kanye West ti o je omo ile America nikan ni o ku ti yoo maa ri ihooho oun bayi o,Kim soro yi nibi igbaradi ayeye igbeyawo re ni ilu France , gbogbo eyin ti e ti ni aworan tabi fidio ihooho Kim nile tele,oun ko lo wa nibe mon oooooooooooooo


Femi Ojewale

Monday, May 19, 2014

T'ORI OLORUN: Adajo kan ni Orile Ede Sudan ni ki won lo yegi fun abileko kan titi emi yo fi bo ni ara re



 N se ni igbe ekun n ta l'otun ati l'osi ni ojo'bo ose ti o koja nigba ti adajo kan ni Orile Ede Sudan ni ki won lo yegi fun abileko kan titi emi yo fi bo ni ara re. Meriam Yahaya Ibrahim , eni odun metadinlogbon ti o loyun sinu ti o ti bimo kan fun oko re yi tele ni won so pe o d'ese nla nitoripe o se igbeyawo pelu omo leyin Kristeni , idi niyi ti won fi ni ki won lo yegi fun un. Huuuummmmm o ga ooo !!!


Onirohin ọkunrin -- Femi Ojewale‎

Sunday, May 18, 2014

Eemo W'olu ooo: ni ilu Ilobu ni ijoba ibile Irepodun ni Ipinle Osun


Laaro ojo'bo ninu ose ti o koja ti awon ara ilu Ilobu ni ijoba ibile Irepodun ni Ipinle Osun ji,n se ni gbogbo olugbe ilu naa n ko ha ha ha nitori pe enu ya won si oun ti o sele naa. N se ni won ba odomokunrin eni ogun odun ti oruko re n je Abdullahi omo ile Tooto ninu ilu naa ti o ti ku si eti saare nibi ti o ti fe ji oku kan ti won sese sin wu,o ti ori bo inu isa oku naa lati faa jade ni oun naa ko ba le jade mo titi o fi ku sibe.Tabi e ko ri nnkan bi ?


Femi Ojewale‎

Omi Tan Leyin Eja Won: owo awon omo ogun JTF te Mejo ninu awon gbemi gbemi Boko Haram

OMI TAN LEYIN EJA WON. Mejo ninu awon iko gbemi gbemi Boko Haram miran ni owo awon omo ogun JTF Nigeria ma tun ti te bayi ni abule Goym ni ijoba ibile Dikwa ni ipinle Borno nibi ti won ti jade wa pelu oko akero Hilux pelu keke alupupu meji lati wa ra onje ati aso . Gege bi arigbamu iroyin ti a gbo lati Olu famous ni pe awon mejo yi ti jewo pe awon omo ile iwe ti won ji ko lojosi wa ninu igbo Sambisa , awon ti owo te naa ti jewo ibi ti awon die wa , eyi lo tun mu ki owo te opolopo won.

Femi Ojewale‎

Owo Palaba S'egi: Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram



Ko din ni Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram ti won bo sowo ibon awon apapo omo ogun JTF ti orile ede yi. Ninu ija naa ti o gbona jan jan ninu igbo ti won n pe ni igbo Lamba , ni ijoba ibile Gwaram ni ipinle Jigawa ni ibon awon soja naa ti gbemi Ogota awon Boko Haram ti gbogbo ileto ti o wa ni agbegbe naa si kan gbinrin gbinrin nigba ti won n gburo ibon lotun losi . Ki Olorun tubo maa d'abo re bo wa oooooo


Femi Ojewale

Wednesday, May 14, 2014

Itan Egungun Ni Ile Yoruba

Egungun je Orisa pataki kan nile Yoruba nigba lailai, sugbon kiise Orisa ile Yoruba rara idi niyi ti enikan ko fi le so oruko eni to da sile bi ti awon Orisa toku bi Sango, Ogun, Oya ati bebe lo. Iwadi miran ni igbagbo lori pe ara orun ni Egungun ni ko je ki won le wa fi oruko eni to da sile ti si ara enia to je ara aye ki awo Egungun mo lo ya. Sugbon loni pupo ninu awon to ngbe Egungun gan ko mo awo Egungun tabi itan bi Egungun se bere gan, bi ose bere ni idile onikaluku nikan lo mo.

Monday, May 12, 2014

Excellent Yorùbá Choral Piece

ST