Tuesday, September 2, 2014

ASE KO S'IBI TI ESE KO SI!!


 Ase ko sibi ti won ki i ti d'ana ale , Sugbon obe lo maa n dun ju ara won lo ni. Ko si ibi ti ese ko si , bi iwa l'aabi se n sele l'arin awa eniyan dudu , bee gele lo n sele l'aarin awon alawo funfun. Bee gan an ni oro ri ni ile Japan ni ijeta nigba ti awon eniyan ba okunrin gende kan nibi ti o ti n fi tipa tipa ba omobinrin eni odun meta kan lo po , awon ogunlogo ero naa ko se meni bee ni won ko se meji , n se ni won mu ofin lowo ara won , dipo ki won fa odaran naa le awon Olopa lowo n se ni won lu u pa , haaaaa , se ori bibe loogun ina ori ni ? O j'esu daran. E pade mi lori Whatsapp jare pelu nomba yi 08034032049. E ma sora ooooooo


Femi

A TI GBO OOO !! Oba Lamidi Adeyemi , Alaafin ti Ilu Oyo


Bi e ko tile pe wa sugbon a ti gbo o , boya le mon pe eleti lu k'ara bi ajere ni ORO TO N LO ati pe oju Olootu t'ole koda o tun to Oko . Gbogbo asamo wa naa ni pe a n fi akoko yi ba baba wa , okan pataki ninu awon Oba ile Yoruba , Iku baba yeye , Oba Lamidi Adeyemi , Alaafin ti Ilu Oyo d'awo idunnu ayeye ojo ibi odun kerindinlogorin (76) ti won se laipe yi ni ilu London. A ki baba e ku orire o . E o pe bi ewe ape , e o fowo pari , e o ferigi j,obi. E ku ori 're o

Femi

Saturday, August 30, 2014

MICHELLE AYA OBAMA.

 Michelle iyawo Aare Orile ede America ni e n wo yi , Omo eniyan dudu ni oun ati oko re , itan so pe nigba ti o wa nile iwe girama awon omobinrin alawo funfun ki I fe joko l'egbe re nitori pe o je alawo dudu , koda ninu ile ibugbe awon akekoo binrin ,(Girls Hostel) won ki I fe ki o sun nibe , bi adete ni won se maa n sa fun omobinrin naa nigba naa. Sugbon ni bayi ori ti gbe de Aafin gege bi iyawo Aare America lati odun die seyin , gbogbo awon to n sa a fun un nigba naa nibo ni won wa bayi. Mo gba ni adura pe Olorun yo so iwo naa di pataki laarin awon ti won ko fe gbo ohun re lati oni lo ati titi laelae

Femi Ojewale

Tuesday, August 26, 2014

EEMO WOLU O: Awon ti'o gbero ati pa awa omo Nigeria


. Awon eniyan wo lo wa nidi pe won gbero ati pa awa omo Nigeria run na , Haba kin lo de. Oro yi lo n jade lenu awon omo Orile ede yi lori ohun ti o sele l'ana. L'ana ni awon kan ti enikeni ko mo eye ti o su won wa oko agbarigo nla (trailer) kan ti o kun fun opolopo eran obo (monkey) ti won ti yan to gbe ti o n ja fonfon wo ilu Kastina lati enu ona ibode Jibia. Opelope awon eso asobode Zone B (Nigerian Custom Service) ti igbakeji Oga agba Assistance Comptroller Gambo Azare ko s'odi lo mu motor n

Femi Ojewale‎

Monday, August 25, 2014

NNKAN N BE O: Oyun osu meje ni inu omo odun mejila.

. Oro Olorun ko ni lo lai se , orisirisi la n ri , bee ni orisirisi la n gbo. Bi o tile je pe bi a ba n wi awon Thomas alaigbagbo kan a maa so pe iro la n pa , sugbon ko ba wu mi ki iru awon bee darapo mo wa lori whatsapp , nibi ti aaye ti gba wa lati fi opolopo aworan ati fidio iroyin wa han araye kedere. Okan tun niyi o , bi o tile je pe a fe fi oruko bo omo odun mejila yi lasiri , a ko mo bi oyun osu meje se de inu omo odun mejila o. Eemo re e ooooo

Femi Ojewale

Saturday, August 23, 2014

O MA SE O! Chibok ti awon Boko Haram ji ko



Haaaa , abiyamo , e ku oro omo , bi eniyan ba je ori ahun ti o ba de ibi ti awon obi awon omo ile iwe Chibok ti awon Boko Haram ji ko ninu osu kerin odun yii ti se apero ni ilu Abuja l'ana yo sunkun kikoro. Nibe ni awon obi awon omo naa ti n ro ijoba apapo pe ki won jowo jare ki won ba awon wa oku awon omo awon jade nitori pe omo won ku , o san ju omo won nu lo , won ni leyin osu merin taa lo le so boya awon omo naa wa laye tabi won ti ku ni , won ni ebe awon si ijoba ni pe ki won jowo ba awon seeto bi oku awon omo naa yo se di riri ki awon le sin won bi o ti to ati bi o se ye , Ni ero tiwa a nigbagbo pe aaye ni awon omo naa yo jade , ijoba apapo naa kuku n gbiyanju , mo si mon pe laipe Olorun a fun won se awon omo naa yo si di riri lola Eledumare.

Femi

Thursday, August 21, 2014

Ẹyin ara wa tootọ, Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.



Ibeere tení ní:
"Darukọ awọn oríṣíríṣí Ila tí a ma nkọ n'ílẹ Yorùbá"
Ẹyín ọjọgbọn, ẹ ba wa da sí

ST