Saturday, April 26, 2014

Ekú déédé ìwòyí o! - Ìbéèrè mi nì

Ekú déédé ìwòyí o!
Èyin èèyàn mi lórí ètò yí, ejòwó ebámi dásí òrò yí, bí àwon baba wa nílè yorùbá báfé júbà won a máa so báyìí pé;
ÌBÀ AKÓDÁ, ÌBÀ ASÈDÁ, ÌBÀ ÀTIWÁSÁYÉ. Ìbéèrè mi nìní; tani akódá?
Tani Asèdá?
Kíni àtiwásáyé?

Thursday, April 24, 2014

ERIN WO. Erin wo, Ajanaku sun bi oke.


 Eyin ka ile erin ti wo , Afemojo ku enu isa n s'ofo............................. Lana ojo ketalelogun , osu Kerin ni iku wole to mu Alhaji Moshood Ayinde (Olorun Esan ) lo. Ojulowo onisowo ,omo Apomu, lo nile yi ao ri o mon , Parakoyi oloselu o digba o, ilu London niku ti pa baba ni eni odun metalelaadorin (73 years). Baba Biola o digba .Iba se pe a ki ku laye , Olorun Esan a ba so pe iku jare re....



Femi Ojewale

ASIRI TU: ni adugbo Aperin ni ilu lbadan


 Laipe yi ni owo te obinrin kan ni adugbo Aperin ni ilu lbadan , nigba ti owo awon Olopa ti o n dagbo mo awon ti won n fi omo s'owo eru te Hellen ati oko re ogbeni Temitope lori esun pe won n fi awon omo k'ogbo k'ogbo ti won ko ti I to omo odun mejidinlogun se ise Asewo . Mo gbe osuba bamba fun Komisana ati awon Olopa ilu Ibadan fun aseyori ise naa. E ku ise o


Femi Ojewale

NNKAN N BE. Ireti obi ni pe ki obi jere omo l'ojo ale


Ireti obi ni pe ki obi jere omo l'ojo ale.Sugbon ni ti Elizabeth ko ma ri bee o, Looto,o lo s'ile iwe alakobere,o lo si girama leyin naa lo wole s'ile iwe Obafemi Awolowo Yunifasiti,lle lfe nibi ti o ti n ko ise imo isegun Oyinbo.o ku bi osu meta pere ki o pari eko re ni awon osika eda kan lo fi tipa tikuuku ba a sun ti won si tun pa a, gege bi a se gbo,won ni omo jeje ni Elizabeth ki o to di pe won da emi re legbodo ti won si yo awon nkan kan lo lara re



Femi Ojewale

Sunday, April 20, 2014

EBI OOOO !! awon Boko Haram

!!! Ninu ose ti a wa yi ni awon Boko Haram se saka ni ibudoko kan ti o gbajumo ni ilu Abuja ti ogunlogo emi si sonu sinu ikolu naa bakan naa ni omilegbe ero farapa ti won si ko won lo si ile iwosan Asokoro nilu Abuja. Sugbon ni bayi o , awon eniyan naa ma ti n kigbe ebi o , ninu oro re Minisita fun eto ilera so pe ojuse jije mimu won wa lowo awon alase ile iwosan naa . Se o ye ki o ri bee ? Oro re e o , eyin omo Nigeria , se ki ebi tun lu won pa ni ?

IDARIJIN NLA NIYI O !!! afi bi igba ti eniyan n wo Sinima ofe ni

 Huumm,afi bi igba ti eniyan n wo Sinima ofe ni gbogbo eniyan se de enu sile ni ojo'bo (Thursday) ti o koja yi ni Orile ede Iran nibi ti won ti fe ye igi fun Bilian ti o pa omo kan soso ti iya arugbo kan bi,o ku iseju aaya mewa pere ki won ye igi fun okunrin apaayan naa,ni iya agba yi yo lokankan,bi awon oluworan se ri iya yi ni opolopo won bu sekun sugbon dipo ki iya yi bu sekun n se lo sunmo eni ti o pa omo re ti o si so pe oun darijin in. O ga oooo


Thursday, April 17, 2014

ODU EJI OGBE – The chant Ori koo da mi ‘re – Ori bless me abundantly


Orisa ma jee nsowo asenu – Orisa do not let me labor in vain
Adifa fun okankan lenirunwo Irunmole – Divinated for 401 + 1 Orisa
Nigbati won ntode orun bo wa si ode aiye
When they were to descend from heaven into the world
Ori lo koko da Orunmila si Oke-Igeti -Ori first created Orunmila in Igeti-Hills
Ori koo da mi ‘re – Ori bless me abundantly
Orisa ma jee n sowo asenu -Orisa do not le me labor in vain

ST