Saturday, August 23, 2014

O MA SE O! Chibok ti awon Boko Haram ji ko



Haaaa , abiyamo , e ku oro omo , bi eniyan ba je ori ahun ti o ba de ibi ti awon obi awon omo ile iwe Chibok ti awon Boko Haram ji ko ninu osu kerin odun yii ti se apero ni ilu Abuja l'ana yo sunkun kikoro. Nibe ni awon obi awon omo naa ti n ro ijoba apapo pe ki won jowo jare ki won ba awon wa oku awon omo awon jade nitori pe omo won ku , o san ju omo won nu lo , won ni leyin osu merin taa lo le so boya awon omo naa wa laye tabi won ti ku ni , won ni ebe awon si ijoba ni pe ki won jowo ba awon seeto bi oku awon omo naa yo se di riri ki awon le sin won bi o ti to ati bi o se ye , Ni ero tiwa a nigbagbo pe aaye ni awon omo naa yo jade , ijoba apapo naa kuku n gbiyanju , mo si mon pe laipe Olorun a fun won se awon omo naa yo si di riri lola Eledumare.

Femi

Thursday, August 21, 2014

Ẹyin ara wa tootọ, Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.



Ibeere tení ní:
"Darukọ awọn oríṣíríṣí Ila tí a ma nkọ n'ílẹ Yorùbá"
Ẹyín ọjọgbọn, ẹ ba wa da sí

Wednesday, August 20, 2014

Oniroyin omo ile America

A gbo so igba nu ni iroyin ti oniroyin omo ile America kan ti awon Musulumi kan mu ni igbekun lati 2012 sugbon ti won du l'orun lana. Onise iroyin Ayaworan ni James Wright Foley je ki awon Musulumi onijaadi kan to mu ni ile Syria. Ninu oro ti awon Musulumi naa so lana ki won to du Foley l'orun bi eran ileya. Won ni awon fe pa Okunrin oniroyin naa lati fi san esan iwa ti ile America hu lati ko ogun ja ile Iraq. Ninu oro igbeyin ti Foley so , o ni oun ti gba kadara toun , o ni ohun ti o kan ka oun lara ju ni pe won ko jeki oun se ojuse oun fun awon Molebi oun titi ti iku gbigbona naa fi de. O ma se ooooo

Tuesday, August 19, 2014

Owo Te Odaran Ni Ilu Eko


Owo awon agbofinro ti won n so papa oko Ofurufu Muritala ni ilu Eko ti te afurasi odaran kan ti won ni o jewo pe won ni ki oun ati awon meji miran wa so bombu si papa oko ofurufu naa pelu ibi pataki meta miran ni ilu Eko ni. Okunrin alabo ara naa ti o je omo odun mejilelogun lo so pe awon iko Boko Haram loun n sise fun ati pe erongba oun ati awon meji yoku ni lati so bombu si papako ofurufu Muritala ati awon ibi pataki bi I meta miran. Ekunrere iroyin n bo laipe.

Tuesday, August 12, 2014

IWA ODAJU: Omobinrin to da ese nla kan ni ilu re

IWA ODAJU. Obinrin ti e n wo foto re yi ni oruko re n je Annie Mpariwa , omo odun mokandinlogoji (39) ni I se koda omo orile ede Zimbabwe ni pelu , Laipe yi ni omobinrin naa da ese nla kan ni ilu re. Koda ese naa buru jai , iwa ika pata pata ni. Gege bi a se gbon , won ni obinrin yi ni arun HIV , o si mo bee , Laipe yi lo gbe omo okan ninu awon ti won jo n gbe inu ile ti o si ti omo naa mole fun odidi ojo meta gbako , ti omo naa ba ti fe maa ke ni yo ba bere si maa fun omo naa ni omu, o si se eyi fun oj

Femi

Monday, August 11, 2014

Fidio: Baba Suwe ni Elebolo


Thursday, August 7, 2014

Ẹyin ara wa tootọ, Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.


Ẹyin ara wa tootọ,
Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.
Ibeere tení ní:
"Darukọ awọn orukọ amutọrunwa tí a ní n'ílẹ Yorùbá"
Ẹyín ọjọgbọn, ẹ ba wa da sí

ST