Tuesday, August 12, 2014

IWA ODAJU: Omobinrin to da ese nla kan ni ilu re

IWA ODAJU. Obinrin ti e n wo foto re yi ni oruko re n je Annie Mpariwa , omo odun mokandinlogoji (39) ni I se koda omo orile ede Zimbabwe ni pelu , Laipe yi ni omobinrin naa da ese nla kan ni ilu re. Koda ese naa buru jai , iwa ika pata pata ni. Gege bi a se gbon , won ni obinrin yi ni arun HIV , o si mo bee , Laipe yi lo gbe omo okan ninu awon ti won jo n gbe inu ile ti o si ti omo naa mole fun odidi ojo meta gbako , ti omo naa ba ti fe maa ke ni yo ba bere si maa fun omo naa ni omu, o si se eyi fun oj

Femi

Monday, August 11, 2014

Fidio: Baba Suwe ni Elebolo


Thursday, August 7, 2014

Ẹyin ara wa tootọ, Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.


Ẹyin ara wa tootọ,
Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.
Ibeere tení ní:
"Darukọ awọn orukọ amutọrunwa tí a ní n'ílẹ Yorùbá"
Ẹyín ọjọgbọn, ẹ ba wa da sí

Saturday, August 2, 2014

OSIKA EDA. Owo ti te e o

Owo ti te e o , ani owo ma ti te e,owo ti te osika eda yen ti o pa omo bibi inu ara re nitori iresi (rice) agolo kan pere.Kingsley Ekerete, eni odun mokandinlogbon (29 years) omo bibi ipinle Akwam Ibon lo sa deede fun omobinrin omo bibi inu ara re lorun pa nitori agolo rice kan , omo odun meje pere ni omobinrin naa ti Kingsley fun lorun pa ti o si gbe oku omo naa lo sinu igbo ti o si sin omo naa sibe , sugbon leyin ojo keta eje omo naa ke fun esan lori baba re,owo awon olopa ipinle Rivers ti te e

Femi.

ASISE NLA: Ni orile ede Ghana

 Ki se iroyin titun mo pe omo odun Mokandinlogun ti oruko re n je Benadicta Yeboah Nahnah ni orile ede Ghana binu pa ara re laipe yi lori pe fidio nibi ti oun ati Okunrin kan ti n ba ara won lopo jade sori intaneeti , Sugbon eko ni mo fe ki a ko nibe , se ori bibe ni oogun ori fifo ni ? Lotito ni pe won jo sere ife , awon mejeeji si gba lati ka a sile ninu fidio , bi oro naa se wa jade lo ya omobinrin naa lenu , Se eyi wa to ohun ti a n para eni si ? Kini oju ko ri ri , omobinrin naa ti o sese pa

Femi

Thursday, July 31, 2014

KABIYESI OLORUN: Ibrahim pade omobinrin arewa kan ti oruko re n je Ameena


. Ase otito ni oro awon agba ti won so pe "Olodumare ko gbagbe enikankan"be e gege ni oro Arif Ibrahim Tambe eni ti ko ga ju ese bata kan abo lo se ri. Laipe yi ni Ibrahim pade omobinrin arewa kan ti oruko re n je Ameena Ahmed eni odun mokanlelogun. Loju ese ti omobinrin yi ri arakunrin yi ni ife rado bo o mole , loju ese lo si konu ife si Ibrahim pe oun fe fe e , o ni ki I wa se fife nikan , oun yo fi se oko ti oun yo maa bimo fun un. Oro yi jo Ibrahim loju lojo naa tori n se ni awon obinrin ma n fi I se yeye.Ibrahim so fun Ameena pe ti yo ba fe oun , ohun ni yoo ma se gbogbo ise ile o , yo ma we oun , yo maa ba oun fo aso , yo si maa gbe igbe oun danu bi ti omode , arabinrin naa si gba be e. Ni bayi Ibrahim pelu Ameena ti di t'oko t'aya o koda Olorun ti fi omo ta won lore , awon mejeeji si n gbe igbe alafia ni iwo oorun India (West of India). Huumm , a se ko si oun ti Olorun ko le se.

Femi.

Wednesday, July 30, 2014

O MA SE O !!! El-Rufai padanu okan ninu awon omokunrin re

Oro yi lo n jade lenu awon ti won sun mon eni ti o ti fi igba kan je Minista Abuja tele , Malam Nasir El-Rufai eni ti o padanu okan ninu awon omokunrin re laaro yi , Hamza El-Rufai ni oruko omokunrin naa n je , eni ti o ku ninu ijamba moto kan ti o sele laaro yi , ORO TO N LO gba a ni adura ki Olorun ba wa tu ebi naa ninu. Ti e ko ba gbagbe ni osu die seyin ni idile yi kan naa padanu omobinrin awelewa kan. A gba ni adura ki Olorun ninu aanu re dawo isele ibi duro lori idile naa.

Femi 

ST