Friday, July 25, 2014

Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.


Ẹyin ara wa tootọ,
Ẹ jọwọ, ẹ ba wa da sí eto aṣalẹ t'ení.
Ibeere tení ní:
"ṣe o ba aṣa Yoruba mu kí obínrín kọ ẹnu ífẹ sí ọkunrín ??"
Ẹyín ọjọgbọn, ẹ ba wa da sí

Tuesday, July 22, 2014

Igbeyawo ara oto ti o sele ni Orile Ede



 Huuummm, bi aye ba n lo si opin orisirisi nkan ti ko sele ri ni yoo ma waye , iru re ni eyi ti o sele ni Orile Ede South Africa laipe yi nibi ti omokunrin omo odun Mesan (9) ti se igbeyawo alarinrin pelu iya agbalagba eni odun mejilelogota (62) Igbeyawo naa dun o si larinrin , sugbon emi o mo oun ti won fe fayo ninu iru igbeyawo bee. Ti e ba fe darapo mo ORO TO N LO ni ori Whatsapp nibi ti a ti n so ede Oyinbo e dara po mo wa pelu nomba yi 08034032049.

Femi

OBI RERE: Chein duro pelu baba re ninu aso oye re



. Ojogbon Chein joi ni e n wo ninu aso oye re yi , leyin opolopo wahala ati ila hilo , Omo pandoro re ma ti gbo o , Chein lo duro pelu baba re yi ninu aso oye re leyin ti o pari eko re ni Yunifasiti Orile ede China . Baba yi lo ta oun gbogbo ti o ni lati ri pe omo oun kawe gboye ni Yunifasiti. A dupe pe omo naa ti gboye bayi , e wo aso ti o wa lorun baba lojo eye omo re nitori pe ko ni aso miran , melo ninu awon obi lo le se eleyi , e jeki awa obi toju awon omo wa o. Whatsapp 08034032049.

Thursday, July 17, 2014

Se Oro Yi Ko Ti l'owo Kan Oselu Ninu Bayi ?

Huum , nje oro to wa nile yi ko ti ni owo kan oselu ninu bayi , ha, Oro awon omo ile iwe Chibok ti awon Boko Haram ji ko pamo mo ni ooo , ni ojo isegun ijeta ni Aare Goodluck Ebele Jonathan pe awon obi awon omo wonyi ati marun ninu awon omo ti won ti jaja bo lowo iko gbemi gbemi Boko Haram naa si ipade , sugbon ti okankan ninu awon obi naa ko yoju si ipade naa ni ilu Abuja , eyi lo wa mu ki ara maa fu ORO TO N LO pe , Se oro yi ko ti l'owo kan oselu ninu bayi ?

Femi Ojewale

Wednesday, July 16, 2014

Eyin eniyan mi ebami fun ogbeni yi ni oruko


Tuesday, July 15, 2014

IRU IWA WO NIYI. Gbogbo eyin eeyan mi ?

 Eyin omo Yoruba atata , iru iwa idojuti wo niyi ni gbangba walia , ki obinrin maa ja ija ajadiju nitori oro okunrin , huuummmm , se o dara beeeeee

Oruko Kan Fun Ogbeni Yii !


ST