|
Seun Fadipe |
Ewi nipasẹ Seun Fadipe
ISESE L'AGBA L'OTU IFE...
Isese l'agba; isese la koko bo: Eleda eni, isese eni ni;
Baba eni, isese eni ni;
Iya eni, isese eni ni;
Ori akoda ajifowora,
Ori apere eni, isese eni ni; Iyawo eni, isese eni;
Omo eni, isese eni.
Ibatan eni, isese eni.
Ilu ta ti bi ni, isese eni ni;
Esije, esije, ilu eni, isese eni ni.
Gbogbo ohun abalaye eni, isese eni ni won nse...
Awon alaimokanmokan eniyan la ma f'enu tenbelu saata isese. Oro eni ti ko ba noni isese dabi asiwere to ni Olorun kosi. E ma jeki a tori olaju tabi esinkesin tabi igbagbo osan gangan, ka wa lo so isese eni nu. Nitori bo pe, bo ya, isese eni npada wa beni wo.
Awon omoran to nmo oyun igbin ninu ikarawun, won a kuku wa bini. A gbodo ma ranti isese eni. Isese l'agba ba ba de Otu Ife nibi ojumo ti nmo wa.
Oro isiti fun gbogbo Omo Odu to da Iwa... E ku ojumo s'odun tuntun o. A juse o...
@Segun fadipe