Thursday, September 11, 2014

OMO AKIN .......Yoruba lo so pe " Omo Ajanaku kii yara



Omo ti Ekun ba bi Ekun ni yo jo" asamo yi lo di'fa fun Ogagun Adeboye Obasanjo omo Yoruba atata ti o tun je Omo bibi inu Aare wa ana Oloye Olusegun Okikiola Obasanjo , eni ti o fara pa lopolopo loju ija nigba ti awon iko ti o n dari fija peeta pelu awon iko Boko Haram ni ijeta , Ninu oro re n'ile iwosan nibi ti o ti n gba itoju lo ti so fun awon oniroyin pe oun ti setan lati tun lo koju awon iko gbemi gbemi naa ti ara oun ba ti ya tan , o ni oun ko beru Boko Haram nitori pe ise ti oun gba ni lati mu ki Orile Ede Nigeria wa ni eyo kan soso , o tun tesiwaju pe koda oun ko ko ki emi oun bo sibe nitori pe eekan soso ni omokunrin maa n ku. Hummmm , nibi ti awon eya miran ti n sa seyin , ti won n y'odi seyin , Omo Aremu bee ni baba re maa n se , o kare , Olorun a maa ti o leyin , o ko ni gbe s'oju Ogun

Femi

Monday, September 8, 2014

Ori To Kẹ: Yoruba bọ, wọn ni ‘Oun gbogbo lọwọ ori


Edumare tun wa fi awọn nka mere-mere se ‘ẹsọ ori’
Bi oju, ahọn, eti, eyin ati ọpọlọ
Oju ni fitila ara, ahọn ni ọrọ, ọrọ nii yọ obi lápò, oun lo tun yọ ọfa lápó
Bi eti o ba gbọ yigin, inu kan o kin bajẹ,
Bẹẹ sini, bi eyin ba ti ka, ile ẹrin ti woo
Ti Yoruba ba sọ wipe ọpọlọ eyan ti jọba, ẹ ma fura si iru ẹni bẹ o.

Sunday, September 7, 2014

KERE KERE , ALABORUN FE DI EWU O!!


 Bi ere bi ere oro naa ma fe maa di otito lo , Awon iko gbemi gbemi Boko Haram ma ti n da nla nla , won ti fo fere kuro ninu igbo Sambisa ti won tedo si tele , won ti n gba ilu lowo awon oba Oke Oya kan ,lara awon ilu ti won ti gba ni a ti ri ilu Bana,Bank ati Gulak ti won wa ni ipinle Borno , bakan naa ni won tun fo fere ti won tun gba ilu Madagali ati ilu Bama ni ipinle Adamawa ti apapo awon ilu ti awon Boko Haram ti gba si je marun ototo bayi , koda won ti ri asia won

Femi

Wednesday, September 3, 2014

A KO NI SI ONJE JE O: oogun tari tari si wo aja yi lara



 Ninu ose ti o koja lo yi ni Baba kan , omo re ati awon meta miran jade laye ni agbegbe kan ni ilu Port Harcourt. Yoruba lo so pe "Ohun to ba wu omo je ....." Baba agba yi lo sakiyesi pe okan lara awon Aja (dog) oun n ku u lo, lo ba paa pe ki awon fi p'ata lai mo pe awon kan ni won fi Oogun tari tari si ara eyin adie ti aja naa n ko je , oogun tari tari yi ti wo aja yi lara ki baba yi to pa a, won fi aja naa se obe . Awon marun lo je obe eran aja naa , leyin wakati die , ni won ba n pariwo inu rirun , won ko won o d'ile iwosan sugbon ki won to d'ele iwosan , Alare ti j'agba , won ti ku patapata , e sora , atenuje ko ni pawa o

Femi

Tuesday, September 2, 2014

O MA SE O - Aye akamara , iku alumuntu



. Hummm , Aye akamara , iku alumuntu. Okan o jokan awon oro wonyi lo n jade lenu awon ti won mo okunrin kan ti won n pe ni Ogbeni Sunday Adejumo , ti o tun je Olori awon eso ile iwe University ipinle Eko (UNILAG) eni ti awon amookun sika kan da emi re l'egbodo ni ojo Eti (Friday) ojo kokandinlogbon osu kejo odun yi , ni ijerin. Gege bi a se gbo , won ni , ni adugbo Akoka ni opopona Oyenuga ni won pa ogbeni Sunday si , ni ile oti kan nibi ti o ti n se faaji. A gba a ni adura ki Olorun te Ogbeni Sunday Adejumo si afefe rere.

Femi

ASE KO S'IBI TI ESE KO SI!!


 Ase ko sibi ti won ki i ti d'ana ale , Sugbon obe lo maa n dun ju ara won lo ni. Ko si ibi ti ese ko si , bi iwa l'aabi se n sele l'arin awa eniyan dudu , bee gele lo n sele l'aarin awon alawo funfun. Bee gan an ni oro ri ni ile Japan ni ijeta nigba ti awon eniyan ba okunrin gende kan nibi ti o ti n fi tipa tipa ba omobinrin eni odun meta kan lo po , awon ogunlogo ero naa ko se meni bee ni won ko se meji , n se ni won mu ofin lowo ara won , dipo ki won fa odaran naa le awon Olopa lowo n se ni won lu u pa , haaaaa , se ori bibe loogun ina ori ni ? O j'esu daran. E pade mi lori Whatsapp jare pelu nomba yi 08034032049. E ma sora ooooooo


Femi

A TI GBO OOO !! Oba Lamidi Adeyemi , Alaafin ti Ilu Oyo


Bi e ko tile pe wa sugbon a ti gbo o , boya le mon pe eleti lu k'ara bi ajere ni ORO TO N LO ati pe oju Olootu t'ole koda o tun to Oko . Gbogbo asamo wa naa ni pe a n fi akoko yi ba baba wa , okan pataki ninu awon Oba ile Yoruba , Iku baba yeye , Oba Lamidi Adeyemi , Alaafin ti Ilu Oyo d'awo idunnu ayeye ojo ibi odun kerindinlogorin (76) ti won se laipe yi ni ilu London. A ki baba e ku orire o . E o pe bi ewe ape , e o fowo pari , e o ferigi j,obi. E ku ori 're o

Femi

ST