Sunday, May 18, 2014

Owo Palaba S'egi: Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram



Ko din ni Ogota (60) omo egbe a seku pani Boko Haram ti won bo sowo ibon awon apapo omo ogun JTF ti orile ede yi. Ninu ija naa ti o gbona jan jan ninu igbo ti won n pe ni igbo Lamba , ni ijoba ibile Gwaram ni ipinle Jigawa ni ibon awon soja naa ti gbemi Ogota awon Boko Haram ti gbogbo ileto ti o wa ni agbegbe naa si kan gbinrin gbinrin nigba ti won n gburo ibon lotun losi . Ki Olorun tubo maa d'abo re bo wa oooooo


Femi Ojewale

Wednesday, May 14, 2014

Itan Egungun Ni Ile Yoruba

Egungun je Orisa pataki kan nile Yoruba nigba lailai, sugbon kiise Orisa ile Yoruba rara idi niyi ti enikan ko fi le so oruko eni to da sile bi ti awon Orisa toku bi Sango, Ogun, Oya ati bebe lo. Iwadi miran ni igbagbo lori pe ara orun ni Egungun ni ko je ki won le wa fi oruko eni to da sile ti si ara enia to je ara aye ki awo Egungun mo lo ya. Sugbon loni pupo ninu awon to ngbe Egungun gan ko mo awo Egungun tabi itan bi Egungun se bere gan, bi ose bere ni idile onikaluku nikan lo mo.

Monday, May 12, 2014

Excellent Yorùbá Choral Piece

Friday, May 9, 2014

IKIRE: Eledumare o ma jeki asirin ( gbomo gbomo)

IKIRE...... Hmmmm, eyin ti enmun gbomo gbomo ema kie sara nitori irin ese elomiran manparo mon ki Eledumare o ma jeki asirin, agbo wipe eni ti won mun gege bibi gbomo gbomo ni kise gbomo gbomo ti awon monlebi re si ti nfi OLOPA (POLICE) ko gbogbo awon aladugbo Sanngo mon opopona ile iwosan ijoba ibile, eyin ti eba ni olode ori etete lo toju won ki won o ma kawon kun gbomo gbomo, iwo ti o ba nrin irin ajo ti oosi mon adugbo ibi ti ounlo kiesara daadaa ki won ma kero wipe gbomo gbomo nie Eledumare koni jeki a sirin Oooooo

Adigun Olori Odo‎

Tuesday, May 6, 2014

Gbomo ni GARAJI ODEYINKA

IKIRE latun wao, ago mi dun ganranran ti mosi gbo wipe won n danasun gbomo gbomo kan ni SANNGO nilu IKIRE lowo lowo, oti jona ti awon eniyan si ti tuka lori re kato debe, enikan tun sare de janajanan wipe won tun ti mun gbomo gbomo miran ni GARAJI ODEYINKA ni AKO nilu IKIRE bakanan, Ogao asiri yin kobo mon,  OLORUN AGBAWA LOWO GBOMO GBOMO ASA AYE KO NI KO WA LOMO LO O00000( ASE 0000000)

E Gbo Naa kinni O maa N'fa Tii Awon Okunrin Kan Maa N'ba Osise Tabi Omo - Odo Iyawo Won Seere Ife???


Eyin Ore Mi, E Gbo Naa kinni O maa N'fa Tii Awon Okunrin Kan Maa N'ba Osise Tabi Omo - Odo Iyawo Won Seere Ife???

Saturday, May 3, 2014

Yoruba sọ wipe: ORUKỌ RERE…...

Yoruba sọ wipe…. o san ju wura ati fadaka lọ
Igbẹ kinkin leti awo gbẹgiri, wọn ka mu kuro kama jẹun lọ
bo’ju ba kuro nbẹ, s'ọkan le kuro nbẹ ni
Orukọ-rere pẹlu owo-nini, orẹ mi, o gba lakaye o
Bi wọn bani o ma ko gbogbo ẹ nmeji -meji
iwọ sọ wipe o ti gbọ, dakun ma jẹ awọn ara ọyọ o tiọ ntikuti o
Yoruba to sọ wipe ko f’oko kan p’ẹyẹ meji
awon nọni wọn tun sọ pe booba leku meji, o pofo kan
gbogbo, isha ni !… isha lẹwon! a tilọ, a tide

ST